Home ÀKỌ̀TUN Àwọn jàǹdùkú yabo ilé Sẹ́nétọ̀ Teslim Folarin, wọ́n kó o ní dúkìá
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 24, 2020

Àwọn jàǹdùkú yabo ilé Sẹ́nétọ̀ Teslim Folarin, wọ́n kó o ní dúkìá

Àwọn jàǹdùkú yabo ilé Sẹ́nétọ̀ Teslim Folarin, wọ́n kó o ní dúkìá

Fẹ́mi Akínṣọlá

Egbìnrìn ọ̀tẹ̀, baà ṣe n paná ọ̀kan ni òmíràn n rú túú.
Ní ọ̀sán ọjọ́ Sátidé ni ìròyìn jáde pé àwọn ọmọ ìsọta kan yabo ilé Sẹ́nétọ̀ tó ń ṣojú ẹkùn ìdìbò ààrin gbùngbùn Ọ̀yọ́.

Olùdámọ̀ràn pàtàkì fún Sẹ́nétọ̀ Folarin, Ọ̀gbẹ́ni YSO Olaniyi sọ fún akọ̀ròyìn pé ní òwúrọ̀ kùtù kùtù ọjọ́ Sátidé ni àwọn jàǹdùkú náà tó tó igba níye, kọlu ilé náà tó wà ní Olúyòlé Estate nílùú Ìbàdàn, tí wọ́n sì kó àwọn nǹkan tí Sẹ́nétọ̀ rà fún ìdẹ̀rùn ará ìlú sálọ,

Lára nǹkan tí wọ́n kó ni ọ̀kadà bíi igba, ẹ̀rọ tó ń lọ ata, fìríìjì, ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń pọ́ táyà ọkọ̀, àti àwọn nǹkan míràn.
Olaniyi ṣàlàyé pé nínú oṣù Kejìlá ọdún 2020 ní Aṣòfin Folarin fẹ́ pín àwọn irin’ṣẹ́ náà fún àwọn èèyàn tí kò rí ọwọ́ họrí ní ẹkùn ìdìbò rẹ̀, àmọ́ àwọn jàǹdùkú ti kó gbogbo rẹ̀ sálọ.
Ó ṣàlàyé pé n’íṣe ni wọ́n kọ́kọ́ fi ìyà jẹ ẹ̀ṣọ aláàbò tó wà nínú ilé náà, tí wọ́n fi ráàyè ṣiṣẹ́ ibi wọn.

Bákan náà ló sọ pé ọwọ́ padà tẹ díẹ̀ lára wọn tó sá pamọ́ sínú ilé náà nígbà tí àwọn ọlọ́pàá dé sí ibẹ̀.

Ọ̀gbẹ́ni Olaniyi sọ pé “abẹ́ ìbùsùn, àti àwọn ibòmíràn bíi kọ́ńbọ́ọ̀dù,ni àwọn jàǹdùkú náà sá pamọ́ sí, kí ọwọ́ tó ó tẹ̀ wọ́n.

“Ọwọ́ tẹ àwọn kan náà láàrin ìgboro, a sì ti fa gbogbo wọn lé àwọn agbófinró lọ́wọ́.

“Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nǹkan ni wọ́n ti kó lọ kí àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò tó dé sí ilé náà.”

Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn tó wà nínú ilé náà lásìkò ìkọlù ọ̀hún fi ara pa, àmọ́ ẹ̀mí ẹnikẹ́ni kò bá lọ. Bákan náà ló sọ pé Sẹ́nétọ̀ Teslim fún’ra rẹ̀ kò sí nílé lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Òkú k…