Home ÀKỌ̀TUN Àwọn jàǹdùkú kọlu ọgbà ẹ̀wọ̀n Ikoyi, agbófinró gba àkóso ibẹ̀
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 23, 2020

Àwọn jàǹdùkú kọlu ọgbà ẹ̀wọ̀n Ikoyi, agbófinró gba àkóso ibẹ̀

Àwọn jàǹdùkú kọlu ọgbà ẹ̀wọ̀n Ikoyi, agbófinró gba àkóso ibẹ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Egbìnrìn ọ̀tẹ̀, bí a ṣe ń paná ìkan ní òmí-ìn ń rú túú.
Ìròyìn ti a gbọ́ ni pé ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní Ikoyi jóná, èyí kò dédé rí bẹ́ẹ̀ bí kò ṣe isẹ́ ọwọ́ àwọn bàsèjẹ́.

Agbenusọ fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Gboyega Akosile tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún akọ̀ròyìn, sọ pé àwọn kan ló kọlu ọgbà ẹ̀wọ̀n náà.

Àwọn kan tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn sọ lórí ayélujára Twitter, pẹ̀lú fídíò kan pé èéfín iná àti ìró ìbọn ni wọ́n kọ́kọ́ ń gbọ́ láti ọ̀nà ibi tí ọgbà ẹ̀wọ̀n náà wà ní àdúgbò Alágbọn ní Lagos Island.
Ní nǹkan bí aago méjìlá ọ̀sán ni ìròyìn náà jáde.

Èyí wáyé lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí àwọn jàǹdùkú kọlu ọgbà ẹ̀wọ̀n méjì nípìńlẹ̀ Edo. Àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n sọ pé ẹlẹ́wọ̀n tó tó ẹgbẹ̀rún méjì, 1,900, ló sá kúrò lásìkò ìkọlù náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…