Home ÀKỌ̀TUN ENDSARS, Àjọ NECO ti sún ìdánwò rẹ̀ síwájú
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 19, 2020

ENDSARS, Àjọ NECO ti sún ìdánwò rẹ̀ síwájú

ENDSARS, Àjọ NECO ti sún ìdánwò rẹ̀ síwájú

Fẹ́mi akinsola

Ṣe wàhálà òhun làásìgbò kìí dúró síbi tó bá rọ̀.
Àjọ olùdarí ìdánwò àṣekágbá ẹ̀kọ́ girama lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, NECO ti sún ìdánwò, rẹ̀ síwájú nítorí ìwọ́de àwọn ọ̀dọ́ káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ń lọ lọ́wọ́.

Àtẹ̀jáde kan tí alukoro àjọ náà, Azeez Sani fi síta lọ́jọ́ Àìkú ṣàlàyé pé níwọ̀n ìgbà tí lílọ bíbọ̀ ọkọ̀ ti ń fara gbá nínú ìwọ́de tó ń lọ káàkiri náà ó ti ṣe ìdíwọ́ pẹ̀lú fún àwọn ìgbésẹ̀ láti ko àwọn ohun èlò ìdánwò káàkiri lọ si gbogbo ibi to yẹ.

Ó fi kún un pé wọ́n ti sún ìdánwò ẹ̀kọ́ nípa kọ̀ǹpútà tó yẹ kó wáyé ní ọjọ́ Ajé ọjọ́ kọkandinlogun oṣù Kẹwàá sí ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù Kọkànlá.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…