Home ÀKỌ̀TUN Tola Oyediran ọmọ Ọbáfẹmi Àwólọ́wọ̀ ti fayé sílẹ̀
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 17, 2020

Tola Oyediran ọmọ Ọbáfẹmi Àwólọ́wọ̀ ti fayé sílẹ̀

Tola Oyediran ọmọ Ọbáfẹmi Àwólọ́wọ̀ ti fayé sílẹ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ikú n pa ni, ilẹ n jẹ eeyan. Iroyin to n tẹ wa lọwọ lo sọ pe Tola Oyediran Awólọ́wọ̀ ti papòdà.

Ọjọ́ kínní oṣù kejìlá ọdún 2020 yìí ni màmá Oyediran tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Ọlóòtú ìjọ ìwọ oòrùn Gúùsù Nàìjíríà nígbà kan rí, Olóye Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ kò bá ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́rin ọdún láyé.

Òun ni omọ Awólọ́wọ̀ tó dàgbà jù, kí ikú tó mú un lọ.

Tola sì ni Alága Ìgbìmọ̀ aláṣẹ ìwé Ìròyìn Tribune títí tí ó fi fayé sílẹ̀.
Dókítà Tokunbọ Dosunmu ṣàlàyé fún akọ̀ròyìn pé Arábìnrin Tola Oyediran Awolowo kò sàárẹ̀ rárá kí ọlọ́jọ́ tó dé.

Ó ní nǹkan bíi aago méjìlá ọ̀sán òní ni ikú wọlé dé wẹ́rẹ́ tó mú ẹ̀gbọ́n òun lọ.

Bákan náà ló ní ẹbí ṣì wà nínú ìrora àti ìyàlẹ́nu pé ṣé gbogbo ẹ̀ ti parí náà nìyẹn ní àsìkò yìí.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…