Home ÀKỌ̀TUN Jàǹdùkú kọlu Gómìnà Oyètọ́lá, ‘èèyàn méjì kú l’Ósogbo
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 17, 2020

Jàǹdùkú kọlu Gómìnà Oyètọ́lá, ‘èèyàn méjì kú l’Ósogbo

Jàǹdùkú kọlu Gómìnà Oyètọ́lá, ‘èèyàn méjì kú l’Ósogbo

Fẹ́mi Akínṣọlá

Orí ló kó Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun,Gbóyèga Oyètọ́lá yọ lásìkò tó fi lọ darapọ̀ mọ́ àwọn olùwọde ENDSARS nílùú Òṣogbo.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọkọ̀ tó báa kọ́wọ̀ọ́rìn ni wọ́n kọlù tí wọ́n sì bàjẹ́ kọjá àlà.

Gómìnà Oyètọ́lá darapọ̀ mọ́ àwọn olùwọde náà lẹ́nu ìrìn tí wọ́n ń rìn láti agbègbè Alékulúwọdò sí Ọlaiya tó sì ń bá wọn kọrin pẹ̀lú ìlérí pé gbogbo ẹ̀dùn wọn ni òun yóó gbé yẹ̀wò.

Ó fi kún un pé ìfẹ̀hónúhàn àlàáfíà ni òun fẹ́ eléyìí tó ní kò ṣàjèjì sí Ìlànà Ìjọba àwarawa.

Àmọ́ṣá ọ̀rọ̀ ni Gómìnà sì ń bá àwọn olùwọ́de náà sọ tó fi di pé àwọn jàǹdùkú kan bẹ̀rẹ̀ sí ní sèkọlù tí wọ́n sì ń yìnbọn pẹ̀lú òkúta sí ọkọ̀ Gómìnà náà.

Àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ Gómìnà ṣàlàyé fún akọ̀ròyìn pé Gómìnà Oyètọ́lá àti ìgbákejì rẹ̀ ye ìṣẹ̀lẹ̀ náà láì farapa ṣùgbọ́n akọ̀ròyìn kan àtàwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ Gómìnà náà kan fara ṣèṣe.

Bákan náà ni ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn olùwọ́de náà kọ́ ló kọlu Gómìnà Oyètọ́lá àti ikọ̀ rẹ̀, bí kò ṣe àwọn jàǹdùkú.

Àwọn iléeṣẹ́ Ìròyìn abẹ́lé kan ń gbé ìròyìn pé èèyàn méjì ló kú lásìkò ìkọlù náà, ṣùgbọ́n àwọn agbẹnusọ fún Ìjọba ṣàlàyé pé, ìjàǹbá ọ̀kadà ló mu ẹ̀mí wọn lọ ṣaájú ìkọlù náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Òkú k…