Home ÀKỌ̀TUN Ìjọba Nàìjíríà gbà láti san N30b fún ASUU
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 17, 2020

Ìjọba Nàìjíríà gbà láti san N30b fún ASUU

Ìjọba Nàìjíríà gbà láti san N30b fún ASUU

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé n tí a kò bá fẹ́ kó bàjẹ́, àwọn àgbà ní ó ní bí a tií ṣe é.
Ní báyìí Ìjọba àpapọ̀ Orílẹ̀ yìí ti gbà láti yọ̀ǹda bílíọ̀nù lọ́nà ọgbọ̀n Náírà, fún àjẹmọ́nú àwọn olùkọ́ Fásitì ní Nàìjíríà.

Ìjọba sọ pé òun yóó san owó náà díẹ̀díẹ̀ láàrin oṣù Karùn -ún ọdún 2021 sí oṣù Kejì, ọdún 2022.

Níbi ìpàdé tí àwọn aṣojú Ìjọba àti àwọn adarí ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ Fásitì, ASUU, tí Ààrẹ wọn, Ọ̀jọ̀gbọ́n Biodun Ogunyemi, ṣe ní alẹ́ Ọjọ́bọ ní wọ́n ti kéde èyí.
Gẹ́gẹ́ bí ìwé Ìròyìn Punch ṣe jábọ, Ìjọba tún sèlérí láti ná bílíọ̀nù lọ́nà ogún Náírà, láti fi ṣe àtúnṣe ètò ẹ̀kọ́ ní Nàìjíríà.

Gbogbo ìgbésẹ̀ yìí ni ìrètí wà pé yóó fi òpin sí ìyanṣẹ́lódì oṣù méje tí ẹgbẹ́ ASUU wà lórí rẹ̀.
Ṣaájú ni Ìròyìn sọ pé Mínísítà fún ọ̀rọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ní Nàìjíríà, Chris Ngige sọ pé ìyanṣẹ́lódì náà fi ààyè sílẹ̀ fún àwọn olùwọ́de End Sars láti má a lo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fún ìwọ́de náà.
Ngige sọ pé láti bí ọ̀sẹ̀ kan ni Ìjọba ti ń ṣiṣẹ́ láti fi òpin sí ìyanṣẹ́lódì náà, tó sì sọ pé àdúrà àwọn ni pé kí ìpàdé tí wọ́n ṣe náà so èṣo rere.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…