Home ÀKỌ̀TUN MC Oluomo, n kò rán àwọn jàǹdùkú sáwọn olùwọ́de l’Èkó
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 15, 2020

MC Oluomo, n kò rán àwọn jàǹdùkú sáwọn olùwọ́de l’Èkó

MC Oluomo, n kò rán àwọn jàǹdùkú sáwọn olùwọ́de l’Èkó

Fẹ́mi Akínṣọlá

Alága ẹgbẹ́ awakọ̀ èrò NURTW ní ìpínlẹ̀ Èkó, Alaaji Musiliu Akinsanya tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí MC Olúọmọ ti ṣàpèjúwe ẹ̀sùn tí àwọn kan fi ń kàn án pé òun ló rán àwọn jàǹdùkú láti da ìwọ́de #ENDSARS rú l’Èkó gẹ́gẹ́ bí irọ́ lásán.

Ó ṣàlàyé nínú fọ́nrán kan tó fi sí ojú òpó abẹ́yefò rẹ̀ pé gbogbo ara ni òun ti fi ti ìwọ́de náà lẹ́yìn láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ nítorí náà òun kò leè sí nídìí ìdarú rẹ̀.

Ó wá fi ègun lé e pé kí iṣẹ́ òun dàrú bí òun bá mọ̀ sí àwọn jàǹdùkú tó lọ kọlu àwọn èèyàn náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Òkú k…