Home ÀKỌ̀TUN INEC kéde èsì ìbò gómìnà níjọba ìbílẹ̀ méjìlá
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 11, 2020

INEC kéde èsì ìbò gómìnà níjọba ìbílẹ̀ méjìlá

INEC kéde èsì ìbò gómìnà níjọba ìbílẹ̀ méjìlá

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn olùdìbò ti tú kẹ̀tíkẹ̀tí láti ṣàmúlò àǹfààní tí wọ́n ní fún yíyan ẹni bí ọkàn an wọn sí orí àlééfa ní ìpínlẹ̀ Òǹdó bákan náà ní Àjọ elétò ìdìbò nílẹ̀ wa, INEC, ti bẹ̀rẹ̀ ìkéde èsì ìbò Gómìnà nípìńlẹ̀ Òǹdó bẹ̀rẹ̀ láti òru ọjọ́ Sátidé sí Àìkú.

Ìbò kíkà náà, tó bẹ̀rẹ̀ ní bíi aago méjìlá ààbọ̀ lóru ọjọ́ Àìkú, ni alámòjútó ètò ìdìbò Gómìnà ní ìpínlẹ̀ Òǹdó, Ọjọ́gbọn Idowu Olayinka, tíì se Ọ̀gá àgbà Fásitì Ìbàdàn, ṣíde rẹ̀.

Nígbà tó ń kí àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ nínú ètò ìdìbò náà káàbọ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Olayinka ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rin ló ti wà nílẹ̀ fún kíkà síta.

Àwọn Ìjọba ìbílẹ̀ náà ni Ifedore, Ile oluji/oke igbo, Irele àti Àkókó North West.
Nínú ọ̀rọ̀ ìkínni káàbọ̀ rẹ̀, Kọmíṣọ́nnà f’ájọ elétò ìdìbò nípìńlẹ̀ Òǹdó, Oluwatoyin Akeju dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn èèyàn tó wà níkàlẹ̀ fún àtìlẹ́yìn wọn, láti ríi dájú pé ètò ìdìbò náà kẹ́sẹjárí .

Alákòóso àpapọ̀ f’ájọ elétò ìdìbò tó ń bójútó ìpínlẹ̀ Òǹdó, Ọ̀mọ̀wé Ademola Ogunmola nínú ọ̀rọ̀ tiẹ̀, wá gbóríyìn f’áwọn olùdìbò, fún bí wọ́n se jẹ́ kí ìlérí Àjọ INEC, láti se àṣeyọrí kọjá ohun tó wáyé nípìńlẹ̀ Edo, di múmuṣẹ.

Ní kété tí ètò kíkà náà bẹ̀rẹ̀ sí ní awọn èsì ìbò Ìjọba ìbílẹ̀ míràn ń wọlé, yàtọ̀ sí ti mẹ́rin tó wà nílẹ̀ ṣaájú.
Nígbà tí yóó sì fi di aago méjì ààbọ̀ òru, àjọ INEC ti kéde èsì ìbò nìjọba ìbílẹ̀ méjìlá nínú méjìdínlógún tó wà nípìńlẹ̀ Òǹdó.

Àwọn Ìjọba ìbílẹ̀ tí wọ́n kéde náà ni Irele, Ilẹ̀ Olúji, Òǹdó East, Ọ̀wọ̀, Àkókó North East, Àkókó South West, Ìdànrè, Àkókó North West, Àkúrẹ́ North, Àkókó South East and Àkúrẹ́ South.

Àwọn Ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́fà yókù tí wọn kò tíì kéde ni Òǹdó West, Odigbo, Okitipupa, Ìlàjẹ, Ẹṣẹ Odò àti Òǹdó West.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…