Home ÀKỌ̀TUN À ń sá àsàlà fún ẹ̀mí wa lọ́wọ́lọ́wọ́- Akọ̀wé ààfin Ṣọun
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 11, 2020

À ń sá àsàlà fún ẹ̀mí wa lọ́wọ́lọ́wọ́- Akọ̀wé ààfin Ṣọun

À ń sá àsàlà fún ẹ̀mí wa lọ́wọ́lọ́wọ́- Akọ̀wé ààfin Ṣọun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjàngbọ̀n kìí dúró síbi tó rọ̀, bí kò ṣe ibi tó le koko.

Hùn! Ẹni orí yọ ìpàdé di Ilé ni ọ̀rọ̀ dà nílùú Ògbómọ̀ṣọ́ níbi tí àwọn ọ̀dọ́ kan ti yabo ààfin Sọun Ògbómọ̀ṣọ́.

Lọ́wọ-lọ́wọ́ bó ṣe ń kàn wá lára ni pé àwọn kan ti yabo ààfin Sọun Ògbómọ̀ṣọ́, Ọba Ọladunni Oyewumi Ajagungbadé kẹta tí wọ́n sì ti ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́.

Ìròyìn sọ pé ṣe ni wọ́n kọ́kọ́ ṣe ìkọlù sí àgọ́ ọlọ́pàá kan ní tòsíi ààfin Sọun kí wọ́n tó ráàyè wọlé sí wọn lára.
Nígbà tí ó ń ṣọ̀rọ̀ pẹ̀lú akọròyìn, akọ̀wé ààfin Sọun Ògbómọ̀ṣọ́, arákùnrin kan tí ó ní orúkọ òun ń jẹ́ Totin jẹ́ kò di mímọ̀ pé ẹni orí yọ ó dilé ni torí àwọn ń sá àsálà fún ẹ̀mí àwọn.

Bákan náà ni Mínísítà fún ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà tó wà láàfin Sọun lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ yí fi hàn pé tòótọ ni ìṣẹ̀lẹ̀ yí wáyé.
Lójú òpó abẹ́yefò Twitter Sunday Dada tó jẹ́ ọmọ bíbí Ogbomoṣo, ó ní àwọn jàǹdùkú ya bo ààfin Sọun tí wọ́n sì di ìpàdé táwọn ń ṣe lọ́wọ́.
Ó ní bí wọ́n ṣe ń sọ òkò, ni wọ́n ń fọ́ ìlẹ̀kùn àti gíláàsì.

Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe gbọ́ àwọn ọ̀dọ́ ti kọ́kọ́ ṣe ìwọ́de lọ sí ààfin Sọun láti fẹ̀hónú hàn lórí ikú Isiaq Jimoh tí wọ́n yìnbọn pa níbi ìwọ́de ENDSARS lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.
Nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ yìí dé ààfin, wọn kò ba nǹkan jẹ́ ṣùgbọ́n kò pẹ́ sí ìgbà tí wọ́n kúrò làwọn jàǹdùkú kan yabo ààfin lásìkò tí Mínísítà àti Sọun ń ṣe ìpàdé.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…