Home ÀKỌ̀TUN Ìwọ́de “End SARS”, Buhari ṣe ìpàdé pẹ̀lú Ọ̀gá ọlọ́pàá
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 10, 2020

Ìwọ́de “End SARS”, Buhari ṣe ìpàdé pẹ̀lú Ọ̀gá ọlọ́pàá

Ìwọ́de “End SARS”, Buhari ṣe ìpàdé pẹ̀lú Ọ̀gá ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà ní n tí a kò bá fẹ́ kó bàjẹ́, ó ní bí hàhá tií ṣe é.
Ààrẹ Muhammadu Buhari ti pàṣẹ fún Ọ̀gá Àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà lórí ìgbésẹ̀ tí yóó gbé lórí ìwọ́de #ENDSARS tó ń lọ káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, lẹ́yìn tí àwọn méjéèjì ṣe ìpàdé lọ́jọ́ Ẹtì.

Ààrẹ Buhari nínú Ìkéde tó fi síta lójú òpó abẹ́yefò Twitter lórí ọ̀rọ̀ náà sọ pé kí àwọn ọmọ Nàìjíríà ó má ṣe ṣiyèméjì lórí ìgbésẹ̀ àtúntò tí àwọn ń ṣe ni’léeṣẹ́ ọlọ́pàá Orílẹ̀ yìí.

Ó ní “gbogbo ìgbà ni wọ́n ń fi tó mi létí lórí ìgbésẹ̀ àtúnṣe tó ń lọ láti fi òpin sí bí àwọn ọlọ́pàá ṣe máa ń fi ìyà jẹ ni, àti àwọn ìwà tí kò tọ́ míràn. Àti láti rí i dájú pé àwọn ọlọ́pàá ń jíyìn iṣẹ́ fún aráàlú.”

Ìpàdé tí Ààrẹ ṣe pẹ̀lú Ọ̀gá Àgbà ọlọ́pàá wáyé lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí àwọn ọ̀dọ́ bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de ojoojúmọ́ láti Ọjọ́rú nípìńlẹ̀ Èkó, àti àwọn ìpínlẹ̀ míràn ní Nàìjíríà.

Buhari sọ pé Ọ̀gá ọlọ́pàá ti gba àṣẹ lọ́wọ́ òun láti gbé ìgbésẹ̀ lórí awuyewuye tó ń wáyé láti ọ̀dọ̀ aráàlú lórí ìwàkiwà tó wà lọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá SARS, àti láti rí i dájú pé àwọn ọlọ́pàá tó hu ìwà tí kò tọ́ fojú winá òfin.

Nínú ọ̀rọ̀ tó kọ sí orí ayélujára Twitter, Buhari bẹ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti mú sùúrù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní ẹ̀tọ́ láti ṣe ìwọ́de lórí ohun tí kò bá dùn mọ́ wọn nínú.

“Olùfọkànṣìn ni ọ̀pọ̀ lára àwọn ọlọ́pàá Nàìjíríà, tó sì ń fi ara ṣiṣẹ́ láti pèsè ààbò fún ẹ̀mí àti dúkìá ní Nàìjíríà, aó sì níí dáwọ́ àtìlẹ́yìn wa dúró kí wọn ó lè ṣe iṣẹ́ wọn.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…