Home ÀKỌ̀TUN Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí Sẹ́nétọ̀ Elisha Abbo san Àádọ́ta mílíọ̀nù fún obìnrin tó fìyà jẹ
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 30, 2020

Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí Sẹ́nétọ̀ Elisha Abbo san Àádọ́ta mílíọ̀nù fún obìnrin tó fìyà jẹ

Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí Sẹ́nétọ̀ Elisha Abbo san Àádọ́ta mílíọ̀nù fún obìnrin tó fìyà jẹ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ẹ̀dá yóó yó tán, tí yóó tiro ẹsẹ̀ méjéèjì máa wá bẹ́kùnbẹ́kùn àpẹrẹ ni ti Sẹ́nétọ̀ tó ń ṣojú ẹkùn ìdìbò Àríwá Adamawa, Elisha Abbo, tí Ilé ẹjọ́ gíga ìlú Àbújá, tó wà ní Maitama, ti dájọ́ pé kí san àádọ́ta mílíọ̀nù Náírà, gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn, fún òṣìṣẹ́ Ilé ìtajà kan tó fi ìyà jẹ.

Oṣù karùn- ún, ọdún 2019 ni fídíò kan jáde s’órí ayélujára, tó sì ṣàfíhàn bí Sẹ́nétọ̀ Abbo ṣe ń kó ìgbájú, ìgbámú fún obìnrin kan ní ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń ta àwọn èròjà ìbálòpọ̀ nílùú Àbújá.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Nàìjíríà ló korò ojú sí ìhùwàsí Sẹ́nétọ̀ náà.

Èyí mú kí ọ̀rọ̀ náà dé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, tí wọ́n sì kọ́kọ́ gbé e lọ sí ilé ẹjọ́ májísírètì kan ní agbègbè Zuba, nílùú Àbújá.

Ṣùgbọ́n, adájọ́ Ilé ẹjọ́ náà, Abdullahi Ilelah, wọ́gilé ẹjọ́ náà, lẹ́yìn tí Abbo kọ̀wé pé òun kò ní ẹjọ́ kankan láti jẹ́.

Arábìnrin náà, Osinibibra Warmate, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀, pe ẹjọ́ míràn sí Ilé ẹjọ́ gíga ìlú Àbújá, tí wọ́n sì fi ẹ̀sùn kan Sẹ́nétọ̀ Abbo pé ó tẹ ẹ̀tọ́ rẹ̀ mọ́lẹ̀.

Onídàájọ́ ilé ẹjọ́ gíga náà, Samira Bature sì ti dájọ́ pé kí Sẹ́nétọ̀ Abbo san mílíọ̀nù lọ́nà àádọ́ta Náírà fún arábìnrin Warnate, láti fi tù ú nínú.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…