Home ÀKỌ̀TUN Ìbànújẹ́ ọkàn ló jẹ́ fún mi bí ẹgbẹ́ NLC ṣe wọ́gilé ìyanṣẹ́lódì – NLC Èkó
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 29, 2020

Ìbànújẹ́ ọkàn ló jẹ́ fún mi bí ẹgbẹ́ NLC ṣe wọ́gilé ìyanṣẹ́lódì – NLC Èkó

Ìbànújẹ́ ọkàn ló jẹ́ fún mi bí ẹgbẹ́ NLC ṣe wọ́gilé ìyanṣẹ́lódì – NLC Èkó

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣe n tó kọjú sẹ́nìkan, ẹ̀yìn ló kọ sẹ́lòmíìn, bíi ìlù u gángan.

Èyí ló mú kí Alága ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ nípìńlẹ̀ Èkó, Comrade Agnes Funmi-Sessi, bu ẹnu àtẹ́ lu bí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lápapọ̀, NLC, ṣe pàṣẹ pé kí wọ́n gbégilé ìyanṣẹ́lódì tí wọ́n fẹ́ gùnlé , tako ọ̀wọ́n gógó epo bẹntíróò àti iná ọba.

Comrade Funmi-Sessi lásìkò tó ń bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ohun tí Ìjọba àpapọ̀ ń ṣe ni láti paná ìyanṣẹ́lódì náà lásìkò yìí.

Ó ní ìbànújẹ́ ọkàn ló jẹ́ fún òun wí pé, àwọn adarí NLC gbọ́ sí Ìjọba lẹ́nu nítorí àwọn ènìyàn ti múra sílẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì tako ọ̀wọ́ngógó náà.

Àmọ́, Alága ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ nípìńlẹ̀ Èkó náà ní, àwọn kò le è ṣe ohunkóhun lẹ́yìn àṣẹ tí àwọn adarí òṣìṣẹ́ pa fún wọn, nítorí náà ni àwọn ṣe paná ìyanṣẹ́lódì ọ̀hún.

“Àwọn òṣìṣẹ́ nípìńlẹ̀ Èkó tí gbaradì láti ṣewode àti ìyanṣẹ́lódì káàkiri ìpínlẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí àtẹjáde láti olú ilé ẹgbẹ́ náà, àmọ́ àwọn adarí wa ti gbàbọ̀dè fún wa”.

“Àdúrà wa ni pé, kí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ má dójú ti àwọn ọmọ Nàìjíríà, pẹ̀lú ìgbésẹ̀ Ìjọba lórí ọ̀wọ́n gógó owó epo bẹntíróò àti iná mọ̀nàmọ́ná.”

“Tí ọsẹ méjì bá pé, tí kò sì sí àṣeyọrí kankan, àwọn ọmọ Nàìjíríà kò ní dá wa l’óùn mọ́, tí a bá pè wọ́n fún irúfẹ́ ìgbésẹ̀ ifẹhọnu han bẹ́ẹ̀.”.

Níbáyìí, Comrade Funmi -Sessi ní àwọn kò ì tíì mọ ohun tó kàn gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́, àmọ́ àwọn ń dúró de àṣẹ ẹgbẹ́ NLC, lórí ohun tó kàn lẹ́yìn tí wọ́n ti wọ́gilé ìyanṣẹ́lódì náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…