Home ÀKỌ̀TUN Oluwo kọ̀ láti sọ̀rọ̀ lórí àwọn afọbajẹ tó fẹ́ yọ ọ́ nípò
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 27, 2020

Oluwo kọ̀ láti sọ̀rọ̀ lórí àwọn afọbajẹ tó fẹ́ yọ ọ́ nípò

Oluwo kọ̀ láti sọ̀rọ̀ lórí àwọn afọbajẹ tó fẹ́ yọ ọ́ nípò

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọba AbdulRasheed Akanbi, Olúwò ti fèsì sáwọn Afọbajẹ méjìlá tí wọ́n kọ̀wé sí Gómìnà Gbóyèga Oyètọ́lá pé kó rọ Olúwò lóyè.

Nígbà tó bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, Olúwò sọ pé òun kò ní ọ̀rọ̀ kankan tí òun lè sọ nípa ọ̀rọ̀ náà.

Àmọ́, ohun tó sọ ni pé àwọn Olóyè kan buwọ́lu ìwé tí àwọn Olóyè náà kọ sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, nígbà tí àwọn míì kọ̀ láti buwọ́lù ú.

Ó ní ọ̀rọ̀ náà tún kan ẹnìkan tó ń wá oyè láti ọ̀pọ̀ ọdún ṣẹ́yìn tí kò rí.

Ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ aráàlú Ìwó ló fọ́n síta láti fi ẹ̀hónú hàn lórí ìgbésẹ̀ àwọn Olóyè tó ń gbìdánwò láti yọ Olúwò ní ipò.

Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ń sọ pé Ọba AbdulRasheed Akanbi ti ṣe ìrànwọ́ ńlá fún àwọn aráàlú.

Wọ́n ní kí Olúwò máa bá Ìjọba rẹ̀ lọ wí pé ó tẹ́ àwọn lọ́rùn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn ló …