Home ÀKỌ̀TUN Àwọn adigunjalè fipá bá ọmọbìnrin lò pọ̀ nínú ṣọ́ọ̀sì
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 26, 2020

Àwọn adigunjalè fipá bá ọmọbìnrin lò pọ̀ nínú ṣọ́ọ̀sì

Àwọn adigunjalè fipá bá ọmọbìnrin lò pọ̀ nínú ṣọ́ọ̀sì

Fẹ́mi Akínṣọlá

Nígbà tí òpin ayé bá ń bọ̀, Onírúurú la ó máa gbọ́, a bí kìí se ìròyìn àgbọ́sọgbánù ní pé àwọn
àwọn adigunjalè yabo ṣọ́ọ̀sì Assemblies of God Church nílùú Abakaliki, ìpínlẹ̀ Ebonyi níbi tí wọ́n ti fipá bá ọmọbìnrin lòpọ̀.

Ìròyìn tí a gbọ́ ni pé ẹgbẹ́ òṣèré àwọn ọ̀dọ́ ló ń ṣe ìgbaradì fún eré orí ìtàgé tí wọ́n fẹ́ ṣe lọ́wọ́ nínú sọ́ọ̀sì táwọn adigunjalè ọ̀hún fi dé sáàrin aago kan sí méjì òru.

Àwọn tó mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà sọ fáwọn akọ̀ròyìn pé àwọn jàǹdùkú náà yìnbọn fún ọ̀dọ́bìnrin kejì ní itan rẹ̀ lẹ́yìn tó kọ̀ kí wọ́n fi ipá bá òun lòpọ̀.

Bákan náà ni a gbọ́ pé àwọn olè náà tún kó nǹkan ṣọ́ọ̀sì
náà lọ.

Nígbà tí akọroyin sàbẹ̀wò sí ṣọ́ọ̀sì ọ̀hún, ọ̀kan lára àwọn alàgbà Ìjọ náà fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pé òtítọ́ ló ṣẹlẹ̀.

Alàgbà náà ṣàlàyé pé àwọn ti fi ọ̀rọ̀ náà tó iléeṣẹ́ ọlọ́pàá létí, bákan náà làwọn sì ti gbé àwọn ọmọbìnrin méjéèjì lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú.

Àlùfáà Ìjọ náà kò sí nílé nígbà tí akọ̀ròyìn sàbẹ̀wò sí ṣọ́ọ̀sì ọ̀hún.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…