Home ÀKỌ̀TUN Mo ti fi ọgbọ̀n ọdún ṣe iṣẹ́ púlọ́ńbà–Babajide Sanwo-olu
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 24, 2020

Mo ti fi ọgbọ̀n ọdún ṣe iṣẹ́ púlọ́ńbà–Babajide Sanwo-olu

Mo ti fi ọgbọ̀n ọdún ṣe iṣẹ́ púlọ́ńbà–Babajide Sanwo-olu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Yorùbá bọ̀, wọ́n ní kí ọ̀rọ̀ tó dayọ̀, ojú a ri.
Bẹ́ẹ̀, ìkòkò tí yóó jata, ìdí i rẹ á gbóná.
Ló dífá fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Babajide Sanwo-olu tó sọ pé òun náà ti ṣe iṣẹ́ púlọ́ńbà rí ní bí i ọgbọ̀n ọdún ṣẹ́yìn.

Gómìnà ò dédé sí aṣọ lójú ọ̀rọ̀ yìí o, ọ̀rọ̀ níí bá mokó morò wa.
Gómìnà Sanwo Olu sọ ọ̀rọ̀ yìí níbi ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́jáde àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 6,252 tó kọ́ iṣẹ́ ọwọ́ ni àwọn ibùdó ìkọ́sẹ́ méjìdínlógún to jẹ́ ti Ìjọba nípìńlẹ̀ náà, ni Gómìnà ti sọ ọ̀rọ̀ yìí.

Sanwo-olu gba àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn obìnrin ní ìmọ̀ràn, láti gbájúmọ́ iṣẹ́ ọwọ́, dípò kí wọ́n ó má a retí pé iṣẹ́ yóò jáde láti ọ̀dọ̀ Ìjọba tàbí iléeṣẹ́ aládàáni.

Kò tán síbẹ̀ o, Sanwo-olu rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jáde náà, láti lo àǹfààní iṣẹ́ tí wọ́n kọ́, fi sọ ara wọn di ẹni tó ń gba èèyàn sí iṣẹ́.

Ó tún rọ̀ wọ́n láti túbọ̀ má a wá ìmọ̀ kún ìmọ̀ l’ẹ́nu iṣẹ́ wọn.
Àwọn iṣẹ́ ọwọ́ bí i irun ṣíṣe, ṣíṣe ara lóge, oúnjẹ ṣíṣè, ìmọ̀ kọ̀ǹpútà, irun gígé, bàtà ṣíṣe, aṣọ rírán, àti àwọn míràn.

Kọmísánà fún ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin àti fífi òpin sí òṣì nípìńlẹ̀ Èkó, Cecilia Dada sọ pé ìwé ẹ̀rí tí yóó fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ní àǹfààní láti wọ iléèwé Ìjọba ìpínlẹ̀ náà, tí wọ́n ti ń kọ́ iṣẹ́ ọwọ́ ni wọ́n yóó fún wọn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Nítorí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀, àwọn aláṣẹ Fásitì KWASU lé olùkọ́ kan dànù

Nítorí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀, àwọn aláṣẹ Fásitì KWASU lé olùkọ́ kan dànù Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn …