Home ÀKỌ̀TUN Ọ̀fẹ́ ní ìjọba ń lo epo bẹntróò àti iná tí mẹ̀kúnù ń forí fá–NLC
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 23, 2020

Ọ̀fẹ́ ní ìjọba ń lo epo bẹntróò àti iná tí mẹ̀kúnù ń forí fá–NLC

Ọ̀fẹ́ ní ìjọba ń lo epo bẹntróò àti iná tí mẹ̀kúnù ń forí fá–NLC

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà ní bí ọ̀rọ̀ ńlá kò bá tíì tán, ńlá kò ní sinmi àròyé.
Ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà,NLC ti kéde wí pé àwọn yóó bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì àti ìfẹ̀hónúhàn káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ láti Ọjọ́ Ajé, ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀.

Adarí iléeṣẹ́ ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ NLC ní ìpínlẹ̀ Èkó, Onyeka Chris lọ́ sọ bẹ́ẹ̀ fún akọ̀ròyìn lásìkò tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìgbaradì wọn fún ìfẹ̀hónúhàn ọlọ́gbọọrọ náà.

Chris ni àwọn òṣìṣẹ́ darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà tó kù káàkiri láti tako ìgbésẹ̀ ìjọba tó fi owó kún owó epo àti iná ọba náà.

Ó ní ìgbésẹ̀ Ìjọba yìí fihàn wí pé kò yé wọn òhun tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń là kọjá káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…