Home ÀKỌ̀TUN Ẹgbẹ́ NULGE Ọ̀yọ́ dìbò yan olóyè ẹgbẹ́
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 23, 2020

Ẹgbẹ́ NULGE Ọ̀yọ́ dìbò yan olóyè ẹgbẹ́

Ẹgbẹ́ NULGE Ọ̀yọ́ dìbò yan olóyè ẹgbẹ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ Ìjọba ìbílẹ̀ NULGE, ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ti dìbò yan àwọn olóye Ìgbìmọ̀ aláṣẹ tuntun fún ẹgbẹ́ náà.

Ètò ìdìbò ọ̀hún tó wáyé lálẹ́ tako àṣẹ iléẹjọ́ tó sọ pé kí wọ́n sì dá ètò ìdìbò náà dúró ná.

Adájọ́ N. C. S. Ogbuanya ti iléẹjọ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ọba nílùú Èkó ló fòte lé ètò ìdìbò àwọn olóye ẹgbẹ́ tuntun.

Ẹjọ́ tó wà nílé ẹjọ́ ọ̀hún dá lé ẹjọ́ tí Ọ̀gbẹ́ni Hakeem Ojo Oyewo pè wí pé wọ́n yọ òun kúrò gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn olùdíje fún ipò Ààrẹ ẹgbẹ́ NULGE.

Òfin yìí sì wà síbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí lè jẹ́ kí wọ́n ṣe ètò ìdìbò mìíràn títí ẹjọ́ náà yóó fi ní ìyànjú nílé ẹjọ́.

Àmọ́, ní ìdájí ni wọ́n dìbò yan Kọ́múréèdì Ayobami Olusegun Adeogun gẹ́gẹ́ bíi Alága ẹgbẹ́ NULGE ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Nígbà tí wọ́n kéde rẹ̀ tán gẹ́gẹ́ bíi ẹni tó jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò náà, Kọ́múréèdì Adeogun sèlérí pé òun kò ní já àwọn ọmọ NULGE kulẹ̀.
Alága tuntun náà sọ pé òun kò ní ṣàì máa tọ ipaṣẹ̀ àwọn tó ti dipò olórí mú nínú àjọ náà tẹ́lẹ̀.

Ó gbàdúrà wí pé kí Elédùwà jẹ́ kí òun rùúure kí òun sọ̀ ọ́ ‘re.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn ló …