Home ÀKỌ̀TUN Erin tún wó lágbo òṣèré! Àwòrò jáde láyé
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 17, 2020

Erin tún wó lágbo òṣèré! Àwòrò jáde láyé

Erin tún wó lágbo òṣèré! Àwòrò jáde láyé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ikú pabírí abírí, abírí kú, ikú pabìrì , ó rọ̀run, ikú pàkọ̀kọ́ omi àgbọn dànù.
Ikú paláhéré, nínú oko.
Ẹnu ò gbàròyìn níjọ́ tíkú ja gbájúmọ́ lólè, èyí gan an ló bí báwọn àgbà òṣèré oní tíátà nílẹ̀ yìí ti ń sọ ọ̀kan ò jọ̀kan ọ̀rọ̀ nípa olóògbé Jimoh Aliu tó papòdà lọ́jọ́bọ, lẹni ọdún mẹ́rìndínláàdọ́rùn ún.

Nínú àwọn èèyàn tó bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ni Ìyá Òòṣà Fọlákẹ Àrẹ̀mú tí a mọ̀ sí Òrìṣábùnmi àti Adébáyọ̀ Salami, Ọ̀gá Bello.

Òrìṣábùnmi banújẹ́ lórí ikú Jimoh Aliu tó sì ní ”Bàbá ni Jimoh Aliu jẹ́ fún wa, Bàbá ni wọ́n jẹ́ fún mi, Bàbá alálùbáríkà ni wọ́n jẹ́ lọ́jọ́kọ́jọ́ ”

Tìbànújẹ́ tìbànújẹ́ ọkàn ló fí sàdúrà pé kí Elédùwà má ṣe fi ọwọ́ ìbàjẹ́ kan gbogbo nǹkan tí Jimoh Aliu fi sáyé lọ.

Bákan náà nínú ọ̀rọ̀ tí Ọ̀gá Bello,Adebayo Salami sọ, ó ní Jimoh Aliyu jẹ́ ẹnìkan tó gbé àṣà lárugẹ.

”Ó ṣe wá láànú pé ikú rẹ̀ wá lásìkò yí. Ẹnìkankan kò le gbàgbé ipa tó kó láti jẹ́ kí eré orí ìtàgé dàgbà sókè.”

Àrélù ni eré tó gbé àgbà ọ̀jẹ̀ Jimoh Aliu sáyé, tí ọ̀pọ̀ sì ní ipa ribiribi tó kó nínú rẹ̀ jẹ́ mánigbàgbé.

Yàtọ̀ sí Arelu, ó tún kópa nínú eré mìíràn bíi:

Ikú Jàre Ẹ̀dá,
Igbá Oró
Àgbáàrìn
Yánpọnyánrin
Ẹwà
Igbó Ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀
Ìrìnkèrindò
Rúkèrúdò
Àjálù
Ọdún 1959 ni Jimoh Aliu bẹ̀rẹ̀ sí ní kópa nínú eré orí ìtàgé nígbà tí Akin Ògúngbè sàbẹ̀wò sí ìlú rẹ̀.

Lọ́dún 1966 tó ti pé ọdún méje tí ó ti lò lọ́dọ̀ ọ Ògúngbè, Jimoh Aliu dá ẹgbẹ́ eré orí ìtàgé tirẹ̀ sílẹ̀ nílùú Ìkàrẹ, Jimoh Aliu Concert Party.
Ó kù nìbọn-ọ́n ró nìròyìn nípa irúnmọlẹ̀ òṣèré tíátà yìí tó bọ agọ̀ sílẹ̀, a kú aráfẹ́rakù, ẹ sì kú ojú lọ́nà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn ló …