Home ÀKỌ̀TUN Hà! Búlúu fiìmù nínú igbó Osun Osogbo
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 15, 2020

Hà! Búlúu fiìmù nínú igbó Osun Osogbo

Hà! Búlúu fiìmù nínú igbó Osun Osogbo

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé bí òpin ayé bá ń bọ̀, onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ ajániláyà àti à gbọ́ ṣe hàà la o máa gbọ́
Irúfẹ́ ìròyìn ìrọ̀lẹ́ ayé ọ̀hún ni ti ọmọkùnrin kan, Tobiloba Jolaosho, ti àwọn ọlọ́pàá ti mú báyìí nítorí pé ó ya fídíò ìbálòpọ̀ nínú igbó Ọ̀ṣun Òṣogbo, tó sì tún fi fídíò náà s’órí ayélujára.

Òṣèré sinimá ìbálòpọ̀, tí àwọn elédè Gẹ̀ẹ́ṣì ń pè ní ‘porn tàbí blue film’ ni Jolaosho, tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ King Tblak HOC.

Ìròyìn sọ pé ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ẹlẹ́ṣìn ìbílẹ̀ nípìńlẹ̀ Ọ̀ṣun ló fi ọ̀rọ̀ tó iléeṣẹ́ ọlọ́pàá l’étí pé, òun rí Jolaosho nínú fídíò náà tó ń hu ìwà ìbàjẹ́ nínú igbó ọ̀hún. Èyí tó le da àlàáfíà ìlú rú.

Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nípìńlẹ̀ Ọ̀ṣun, Oplalola Yemisi sọ fún akọ̀ròyìn pé wọn ó gbé Jolaosho lọ sílé ẹjọ́, tí ìwádìí bá parí.

Wọ́n fi ẹ̀sùn kàn án pé níṣe ló múra bí abọ̀rìṣà Ọ̀ṣun, tí òun àti ọmọbìnrin kan tó wà ní ìhòòhò sì jọ ní ìbálòpọ̀ nínú ojúbọ náà, l’ósù Keje, ọdún 2020.

Oríṣìríṣi fídíò ìbálòpọ̀ náà ló kún orí ayélujára abẹ́yẹfò Twitter ọmọkùnrin ọ̀ún, tó ti ní olólùfẹ́ tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n tó ń tẹ̀lé e lórí ayélujára.

Ò sì tún ní ìtàkùn àgbáyé tí àwọn èèyàn ti má ń san owó láti wo àwọn fídíò náà.

Nígbà tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún akọ̀ròyìn, Àràbà ìlú Òṣogbo, tó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alámòjútó ẹ̀sìn ìbílẹ̀ nílẹ̀ Yorùbá, Olóyè If áyẹmí Elébuìbọn, sọ pé níṣe ni ọmọkùnrin náà fi kele àti ọ̀pẹ̀lẹ̀ kọ́rùn, tó sì lọ bá àwọn obìnrin ṣe aṣemọ́ṣe.

“A ò mọ nǹkan tó kọlu ọmọkùnrin náà. Bí ìgbà tí èèyàn fẹ́ da ẹrẹ̀ sí ibi tí a pè ní ibi mímọ́ ni nǹkan tó ṣe.

“Ibi tí gbogbo èèyàn ti ń wá káàkiri àgbáyé láti ṣètùtù, ló lọ ọ mu abawọn ba.”

Ẹlẹ́buùbọn sọ pé ọwọ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti tẹ ọmọkùnrin náà.

“Ó ti ba ayé ara rẹ̀ jẹ́, orí rẹ̀ ti gbálẹ̀ báun, nítorí ìwà tó hù yìí.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…