Home ÀKỌ̀TUN Ìjọba àpapọ̀ yóò fòfin de títà àti rírà ọtí inú ọ̀rá
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 14, 2020

Ìjọba àpapọ̀ yóò fòfin de títà àti rírà ọtí inú ọ̀rá

Ìjọba àpapọ̀ yóò fòfin de títà àti rírà ọtí inú ọ̀rá

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé kò sí n tí ẹ̀dá fàsejù kún tí kìí já sá bùù
Gbogbo àwọn ọtí inú ọ̀rá àti inú ìgò wọ̀nyí ni Ìjọba àpapọ̀ ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti fi òfin dè láìpẹ́, ìyẹn bí ọ̀rọ̀ tí olùdarí àgbà àjọ tó ń gbógun ti ìlòkulò ohun jíjẹ àti òògùn, lórílẹ̀-èdè Nàíjíríà, NAFDAC, Ọ̀jọ̀gbọ́n Mojisọla Adeyẹye ṣe sọ.

Àjọ NAFDAC ni Ìjọba àpapọ̀ fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ yìí nítorí ipa tí mímu ọtí lọ́nà tí kò tó̀nà ń mú bá ìlera ìlú pẹ̀lú ìgbáyégbádùn aráàlú.

Ó ní bí àwọn èèyàn ṣe ń l’áǹfàní láti mu ọtí wọ̀nyí nígbà kúùgbà tó bá wù wọ́n nínú ọ̀rá pélébé pélébé àti ìgò kéékèké ń ṣe ọ̀pọ̀ àkóbá fún àwùjọ pàápàá jùlọ bí ìwádìí ti ṣe fihàn pé àwọn èròjà yìí ló fihàn pé ohun ló ń ṣokùnfà bí àwọn èèyàn ṣe ń mu ọtí bí òjò ẹnu ìgbàṣọ̀rọ̀ láwùjọ yìí.

Ó ní Ìjọba ti kọ́kọ́ fòfin sílẹ̀ fún àwọn tó ń pọn ọtí inú ọ̀rá pélébé àti ìgò kékéke ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2020 pé kí wọ́n dín ìwọ̀n tí wọ́n ń ṣe jáde kù pẹ̀lú ìdá àádọ́ta nínú ọgọ́rùn, (50%) gẹ́gẹ́ bí ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ láti dẹ́kun àwọn ọtí inú ọ̀rá náà.

Àjọ ìlera agbaye, WHO ti gbé e síta nínú ìwádìí kan pé èèyàn mílíọ̀nù mẹ́ta ló ń kú lọ́dún nítorí ọtí mímu.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …