Home ÀKỌ̀TUN Iléeṣẹ́ ààrẹ sọ̀kò ọ̀rọ̀ padà sí Obasanjo
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 13, 2020

Iléeṣẹ́ ààrẹ sọ̀kò ọ̀rọ̀ padà sí Obasanjo

Iléeṣẹ́ ààrẹ sọ̀kò ọ̀rọ̀ padà sí Obasanjo

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kò jọ pé dúkùú tó wà láàrin ilé iṣẹ́ Ààrẹ Orílẹ̀ yìí àti Olóyè Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ ti jẹ rodò múmi o, bí Iléeṣẹ́ Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti sọ̀kò ọ̀rọ̀ padà sí Ààrẹ àná, Olúsẹ́gun Ọbásanjọ́ pé òun gan an ló ń gbé ìgbésẹ̀ láti mú ìpinnu bá Nàìjíríà.

Garba Shehu tó jẹ́ olùdámọ̀ràn Ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn ni ó fèsì yí ní ìdáhùn sí ọ̀rọ̀ tí Ọbásanjọ́ ṣọ pé Nàìjíríà ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ lábẹ́ Ìjọba Buhari.

Shehu sọ pé Buhari ń tún Nàìjíríà ṣe ni àti pé Ọbasanjọ ló ń mú ìpínyà bá orílẹ̀-èdè náà.

Èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí iléeṣẹ́ Ààrẹ lábẹ́ Ìjọba Buhari yóó máa tako ọ̀rọ̀ Ààrẹ àná Ọbasanjọ .

Nínú àtẹjáde tuntun yìí, Shehu ní ohun tó yẹ Ọbasanjọ gẹ́gẹ́ bí àgbà ìlú ní kò dábàá ọ̀nà àti yanjú ìpèníjà tó ń bá Nàìjíríà fínra dípò bó ti ṣe ń rú iná sí ìpinyà lábẹ́ ẹ̀sìn àti ẹ̀yà.

Garba tún mẹ́nubà bí Ààrẹ Buhari ṣe mú ọkàn akin láti yọ owó àfikún epo rọ̀bì táa mọ̀ sí ”subsidy” eléyìí tí Ìjọba Ọbasanjọ dá lábàá ṣùgbọ́n tí wọ́n kò ṣọkàn akin láti ṣọ ọ́ di mímúṣẹ́.

Ó tún mẹ́nubà ìdàgbàsókè tí Ìjọba Buhari ti mú bá Nàìjíríà nípa pípèsè àyíká tó fààyè gba káràkátà àti ìdúnadúrà pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ òkèèrè.

Ó sọ pé pẹ̀lú bí Buhari ti ṣe ṣe àṣeyọrí tó yìí, kò jẹ́ ìyàlẹ́nu pé àwọn olóṣèlú tí kò ní àṣeyọrí lásìkò wọn yóó máa jowú Ààrẹ Buhari.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…