Home ÀKỌ̀TUN Típà tẹ dẹ́rẹ́bà pa ní Ẹ̀pẹ́
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 12, 2020

Típà tẹ dẹ́rẹ́bà pa ní Ẹ̀pẹ́

Típà tẹ dẹ́rẹ́bà pa ní Ẹ̀pẹ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àdúrà ká ràjò, ká mórí délé náà ni kóówá máa ń gbà, ṣùgbọ́n kò jọ pé àdúrà yìí gbà fún àwọn ìdílé tó forí sọta ìjàǹbá ọkọ̀ kan to wáyé lágbègbè ojú ọ̀nà márosẹ̀ Lekki sí Ẹ̀pẹ́ èyí tó rán èèyàn kan lọ sọ́run.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹjáde kan tí àjọ LASEMA fi síta, wọ́n dóòlà ẹ̀mí èèyàn kan bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé òkú èèyàn mìíràn kan jáde níbi ìjàǹbá náà.

Ìjàǹbá ọkọ̀ náà kan ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Camry kan tí nọ́ńbà rẹ̀ jẹ́ KSF920 FF tí ọkọ̀ akóyanrìn típà kan ti nọ́ńbà rẹ̀ jẹ́ ENU 576 ZZ tó kó òkúta lọ rọ́ lù, tó sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀.

Lágbègbè Alasia bus stop ní Márosẹ̀ Lekki sí Ẹ̀pẹ́; Àjọ LASEMA sì jẹ́ kó di mímọ̀ pé ìjánu ọkọ̀ akóyanrìn ló sọ iṣẹ́ sílẹ̀ tó fi lọ kọlu ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà, tó sì tẹ awakọ̀ rẹ̀ pa.

Èèyàn méjì ló wà nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà nígbà tí ìjàǹbá náà wáyé, èèyàn kan kú, èèyàn kan yókù sì ń gba ìtọ́jú

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …