Home ÀKỌ̀TUN Ohun èlò fún ìdìbò Òǹdó jóná mọ́lé
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 12, 2020

Ohun èlò fún ìdìbò Òǹdó jóná mọ́lé

Ohun èlò fún ìdìbò Òǹdó jóná mọ́lé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ohun èlò fún àyẹ̀wò káàdì àwọn olùdìbò ló ti jóná mọ́lé lólú iléeṣẹ́ àjọ elétò ìdìbò orílẹ̀èdè Nàìjíríà, INEC ní ìpínlẹ̀ Òǹdó tó wà nílùú Àkúrẹ́.

Gẹ́gẹ́ bí, ìròyìn ṣe sọ, ní àṣálẹ́ Ọjọ́bọ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wá’yé.

Amúgbálẹ́gbẹ̀ fún Alága àjọ INEC lórí ètò ìròyìn, Rotimi Oyekanmi fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún iléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé kan lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà pé lóòótọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.

Ọ̀kan lára àwọn Kọmíṣọ́nnà àgbà fájọ INEC, Amòfin Festus Okoye tó wà ní ìpínlẹ̀ Òǹdó lọ́wọ́ báyìí lori lórí ọ̀rọ̀ ìdìbò náà la gbọ́ pé ó sá kíjo kíjo lọ sí olú iléeṣẹ́ àjọ INEC náà láti mọ bí ọwọ́jà rẹ̀ ṣe pọ̀ tó.

Àwọn òṣìṣẹ́ panápaná tètè dé síbi ìṣẹlẹ ọ̀hún láti bu omi pa iná náà eléyìí tó ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jó inú agolo ìkẹ́rù kọ̀ǹténà tí wọ́n kó àwọn ẹ̀rọ àyẹ̀wò káàdì olùdìbò náà sí

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé kò sí ẹni leè sọ ní pàtó bí iná náà ṣe bẹ̀rẹ̀ àti ohun tó ṣokùnfà rẹ̀, Amòfin Okoye ti fi dá aráàlú lójú pé ìwádìí yóó wáyé láti le mọ ohun tó ṣokùnfà ìjàǹbá iná ọ̀hún.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…