ìwà àbùkù yìí t’ẹrọfọ bá gbogbo ọmọ Oodua–: Fani-Kayode
ìwà àbùkù yìí t’ẹrọfọ bá gbogbo ọmọ Oodua–: Fani-Kayode
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àṣà kò ní torí èmi bàjẹ́ . Èèyàn tó ta aráalé rẹ̀ lẹ́gbẹ̀fà, kò le è ri rà légbèje.
Awuyewuye tó ń wáyé lórí ìkínni láàrin Ọọ̀ni tìlú Ilé Ifẹ̀, Ọba Adeyeye Ẹnitan Ògúnwùsì àti asáájú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Aṣíwájú Bola Ahmed Tinubu, sí ń tẹ̀síwájú lórí ayélujára.
Níbáyìí, mínísítà tẹ́lẹ̀ fétò ìrìnnà, Femi Fani-Kayode náà ti dá sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lójú òpó abẹ́yefò Twitter rẹ̀ l’ọ́jọ́rù.
Nígbà tó ń ṣọ̀rọ̀ lórí bí Tinubu se jókòó, nígbà tí Ọọ̀ni ń kí i lórí ìdúró, Fani-Kayode ní ọ̀rọ̀ sùnnùkùn ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ ká fi ojú sùnnùkùn wò ó.
Fani-Kayode ní “Ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣàfihàn ìwà àbùkù àti ọ̀yájú kìí ṣe sí ọmọ bíbí ìlú Ile Ife, àmọ́ ìwà náà tàbùkù gbogbo ọmọ ilẹ̀ Yorùbá lọ́kùnrin àti lóbinrin.”
Mínísítà tẹ́lẹ̀ náà fikún pé, ojútì ńlá gbáà ni ìhùwàsí ọ̀hún, léyìí tó yẹ kó pa ni lẹ́kún.
Fani-Kayode wá ń bèèrè pé ṣé asáájú olóṣèlú lẹ́kùn àríwá Nàìjíríà leè kọ̀ láti dìde kí ọba alayé níbẹ̀?
Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo
Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …