Home ÀKỌ̀TUN Tí òṣèré tíátà yóó fí kú, eré ní ń ṣe–Ibrahim Chatta:
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 11, 2020

Tí òṣèré tíátà yóó fí kú, eré ní ń ṣe–Ibrahim Chatta:

Tí òṣèré tíátà yóó fí kú, eré ní ń ṣe–Ibrahim Chatta:

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìlúmọ̀ọ́ká òṣèré tíátà, Ibrahim Chatta ti dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn èèyàn tó se aájò rẹ̀ lórí àwòrán tó gbé sójú òpó Sítágíràmù rẹ̀ lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.

Nínú àwòrán náà ni Chatta ti wà lórí ìbùsùn, tí wọ́n ń fa omi àti òògùn sí i lára.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló rò pé ó ń se àìsàn ló se wà nílé ìwòsàn láì mọ̀ pé eré sinimá lásán ni.

Àmọ́ nígbà tó ń f’èsì lórí àwòrán náà, àti bí ọ̀pọ̀ èèyàn se fi ìfẹ́ hàn sí i, Chatta ní àwòrán náà ló fara jọ òwe tó ní ” Ẹ́ jẹ́ ká dijú, ká se bí ẹni tó kú, ká wo ẹni tí yóó sunkú ẹni.”

Ó wá dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ tí wọ́n pè, tàbí gbàdúrà fun nígbà tí wọ́n rí àwòrán òun, ó ní àwọn náà kò ní sàìsàn.

Bákan náà ló fi ohùn ránṣẹ́ sí àwọn akẹẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n dìjọ ń ṣiṣẹ́ tíátà pé kí wọ́n máa ṣúgbàá akẹẹgbẹ́ wọn tó bá gbé irú àwòrán báyìí síta, kí wọ́n sì wádìí bóyá eré ni ọ̀rọ̀ náà àbí òtítọ́.

Àgbà òṣèré tíátà náà ní “Tí onítíátà yóó fi kú, eré lásán ni wọn yóó rò pé ó ń se.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…