Home ÀKỌ̀TUN Kofi-19, Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní àgbéga kíláàsì
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 9, 2020

Kofi-19, Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní àgbéga kíláàsì

Kofi-19, Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní àgbéga kíláàsì

Fẹ́mi Akínṣọlá

ìpínlẹ̀ Ògùn ti kéde ìgbéga sí kíláàsì tó kàn láì ṣe ìdánwò fún àwọn ọmọ Ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama ìpínlẹ̀ náà ní kété tí wọ́n bá padà ṣẹ́nu ẹ̀kọ́ wọn.

Bákan náà ló tún kéde ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù Kẹsàn án, ọdún 2020 gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí àwọn ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ yóó di ṣíṣí padà.

Agbẹnusọ fún Gómìnà Ìpínlẹ̀ náà, Kunle Somorin ló kéde bẹ́ẹ̀ nínú àtẹjáde kan tó fi ṣọwọ́ sí àwọn akọròyìn.

Ó ní Gómìnà Dapo Abiodun ti buwọ́lù ṣíṣí gbogbo Ilé ẹ̀kọ́ padà bẹ̀rẹ̀ láti Ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ títí dé àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga.

Somorin fi kún un pé Ìjọba ti setán láti ṣí àwọn ilé ẹ̀kọ́ náà ní ìbámu pẹ̀lú Ìlànà tó rọ̀ mọ́ Kofi-19.

Gẹ́gẹ́ bí àlàkalẹ̀ ṣíṣí ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún ṣe lọ, àwọn ọmọ Ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ láti ìpele kínní sí ìkẹta yóó lọ ilé ẹ̀kọ́ lati aago mẹ́jọ òwúrọ̀ sí mọ́kànlá, nígbà tí àwọn tó wà ní ìpele kẹrin sí ìkẹfà yóó lọ láti aago méjìlá ọ̀sán sí aago mẹ́ta.

Àwọn ti ilé ẹ̀kọ́ girama láti ìpele kínní sí ìkẹta àkọ́kọ́ yóó kẹ́kọ́ọ̀ láti aago mẹ́jọ sí mọ́kànlá òwúrọ̀, nígbà tí àwọn tí ìpele kínní sí ìkẹta kejì yóó lọ ilé ẹ̀kọ́ láti aago méjìlá ọ̀sán sí mẹ́ta.

Somorin ṣàlàyé pé àwọn tó ń lọ ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọwọ́ yóó máa kẹ́kọ́ọ̀ bí wọ́n ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀, láti aago mẹ́jọ òwúrọ̀ sí méjì ọ̀sán.

Nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Ilé ìwé gíga ní àǹfànì láti ṣí Ilé ẹ̀kọ́ padà ní ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù Kẹsàn án, ọdún 2020, ṣùgbọ́n ìgbésẹ̀ náà wà lọ́wọ́ àwọn adarí Ilé ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀.

Ní ti àwọn ọmọ Ilé ẹ̀kọ́ láti ọmọ ọdún mẹ́ta sí márùn ún, ó ní wọn kò l’áǹfàní láti padà sílé lásìkò yìí.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ girama tó wà ní ìpele kẹta àkọ́kọ́ yóó tẹ̀síwájú sí ìpele kínní ẹlẹẹkeji láì ṣe ìdánwò, wọn yóó ṣe ìdánwò BECE nínú oṣù Kẹwàá ọdún 2020

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …