Home ÀKỌ̀TUN Ilé ẹjọ́ fi Sunday Shodipe, pamọ́ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 5, 2020

Ilé ẹjọ́ fi Sunday Shodipe, pamọ́ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n

Ilé ẹjọ́ fi Sunday Shodipe, pamọ́ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀rọ̀ afurasí Sunday Shodipe l’Ákínyẹlé tí di èkuru ọ̀ràn ti wọ́n ń sáré kò má sẹ́kù, tí tún ń gbọnwọ́ rẹ̀ sínú awo.
Ṣe kójú ó tó fọ́ la tií kìlọ̀ òkò, Ilé ẹjọ́ Májísírètì àgbà kan nílù Ìbàdàn ti ran Sunday Shodipẹ, afurasí t’ọ́wọ́ ọlọ́pàá tẹ̀ lórí ikú ọ̀wọọwọ̀ọ́ lágbègbè Akínyẹlé nílù Ìbàdàn lọ sí rìmáǹdì ọgbà ẹ̀wọ̀n, lórí ẹ̀sùn pé ó ṣekúpa arábìnrin Funmilayọ Ọladeji.

Adájọ́ Májísírètì àgbà, Patricia Adetuyibi kò gba ẹ̀bẹ̀ ‘o jẹ̀bi tàbí o kò jẹ̀bi’ lẹ́nu afurasí náà kí ó tó ní kí wọ́n lọ fi sí àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà títí di ìgbà tí iléeṣẹ́ ètò ìdájọ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ yóó fi wáyé.
Adájọ́ Májísírètì náà wá sún ìtẹ̀síwájú ìgbẹ́jọ́ náà sí ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹwàá, ọdún 2020.

Olùpẹ̀jọ́ jẹ́ kó di mímọ̀ fún ilé ẹjọ́ náà pé Ọladeji ti Sunday pa lẹ́yìn tó sá kúrò láhàámọ ọlọ́pàá ni wọ́n ṣì torí rẹ̀ gbé e wá síwájú ilé ẹjọ́.

Bí ẹ kò bá gbàgbé, Sunday Shodipẹ ti kọ́kọ́ jẹ́wọ́ pé òun lòun pa Barakat, Grace, Azeezat àtàwọn méjì míràn, kí ọwọ́ ọlọ́pàá tó tẹ̀ẹ́, tó sì tún sá láhàámọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn ló …