Home ÀKỌ̀TUN Àwọn aṣẹ́wó dín dùǹdú ìyà fún Ẹ̀fáńjẹ́líìsì
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 4, 2020

Àwọn aṣẹ́wó dín dùǹdú ìyà fún Ẹ̀fáńjẹ́líìsì

Àwọn aṣẹ́wó dín dùǹdú ìyà fún Ẹ̀fáńjẹ́líìsì

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn aṣẹ́wó ti lu ẹ̀fáńjẹ́líìsì dákú l’Éjìgbò n’ílùú Èkó o, Wọ́n ní ó kọjá ààyè rẹ̀ nípa wíwàásù ní ilé aṣẹ́wó àwọn.

Ẹ̀fáńjẹ́líìsì Mathew yìí ni wọ́n ní pé ó ń pariwo ‘ẹ yí padà kúrò nínú gbogbo ìwà yín ‘

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí ọ̀kan lára àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú rẹ̀ sọ, wàhálà náà bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ẹ̀fáńjẹ́líìsì náà dúró níwájú ìlú mọ̀ọ́ká ilé ìtura kan tó wà ní Èjìgbò tó sì bẹ̀rẹ̀ ìwàásù fún àwọn olówòo nọ̀bì náà àtàwọn oníbàárà wọn pé kí wọ́n fi àwọn ìwà ẹ̀sẹ̀ ọwọ wọn gbogbo sílẹ̀.

Ẹ̀fáńjẹ́líìsì náà tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Mathew wà pẹ̀lú iléèjọsìn kan tí àwọn èèyàn fẹ́ràn púpọ̀ ní ìlú Èjìgbò ní èyí tí kò mọ̀ pé ìrìnàjò ìwàásù ọjọ́ náà leè di wàhálà.

Gẹ́gẹ́ bí ohun ti àwọn ìwé Ìròyìn abẹ́lé kan sọ, ọ̀pọ̀ ìgbà àtẹ̀yìnwà ni wọ́n ti ṣèkìlọ̀ fún un pé kó jìnà sí agbègbè tí wọ́n ti ń ná òwò wọn nígbà kúùgbà tó bá ti ń wàásù.

Ní ọjọ́ tí a ń wí yìí, wọ́n lu ẹ̀fáńjẹ́líìsì náà débi pé ó yọ́run bọ̀ nígbà tó dákú.

Aládùgbóò míràn ṣàlàyé pé kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí yóó wàásù wá sí ilé ìtura náà,sùgbọ́n kìí súnmọ́ wọn púpọ̀ tó bí ó ṣe ṣe lọ́jọ́ náà tí èṣù tapo síná.

Ọ̀pọ̀ọ àwọn Aládùgbóò ló sọ pé ní ìwòye ti wọn, ẹ̀fáńjẹ́líìsì yìí tí gbé sààráà kọjá oríta nípa pé ó kọjá ààyè rẹ̀ nítorí pé “òun fúnra rẹ̀ mọ̀ pé ibi àìmọ́ ni agbègbè náà” ni Èjìgbò.

Bẹ̀ǹbẹ́ ò jìyà tójọ́ọ yídíì ni ìyá tó jẹ ẹ̀fáńjẹ́líìsì yìí lọ́jọ́ náà tó ràrìn fẹsẹ̀ sí.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn ló …