Home ÀKỌ̀TUN Òfin tako ìbálòpò̩ inú mótò –Ọ̀gá Ọlọ́pàá
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 2, 2020

Òfin tako ìbálòpò̩ inú mótò –Ọ̀gá Ọlọ́pàá

Òfin tako ìbálòpò̩ inú mótò –Ọ̀gá Ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti tako ọ̀rọ̀ Ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá àpapọ̀ wí pé kìí se ẹ̀sẹ̀ láti ní ìbálòpọ̀ nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ní ìta gbangba.

Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Èkó, Imohimi Edgal tó fi èyí léde nínú àtẹjáde, bu ẹnu àtẹ́ lu ọ̀rọ̀ tí Ọ̀gá ọlọ́pàá Abayọmi Shogunlẹ sọ ní Ọjọ́ Ìṣẹ́gun pé àwọn ọmọ Nàìjíríà lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin láti ní ìbálòpọ̀ nínú ọkọ̀ ní òjútáyé.

Edgal ní ilé iṣẹ́ ètò ìdájọ́ ní ìpínlẹ̀ Èkó ti gba ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ní ìmọ̀ràn wí pé ohun ìtìjú àti ohun tó ba ni lójú jẹ́ ni kí akọ àti abo má a bá ara wọn ní ìbálòpọ̀ ní ìta gbangba.

Ó fikún un pé ìwé òfin ìpínlẹ̀ Èkó tó níí se pẹ̀lú ìwà aitọ láwùjọ sọ pé ẹni tó bá wu irú ìwà bẹ́ẹ̀ láwùjọ yóó fi ẹ̀wọ̀n ọdún méjì sí mẹ́ta jura gẹ́gẹ́ bí ìwé òfin tó nííse pẹ̀lú ìhùwàsí láwùjọ tó wà ní Section 134 (a) àti section 136 ti ìwé òfin ìpínlẹ̀ Èkó.

Kọmísọ́nnà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó náà wá pàrọwà sí àwọn aráàlú ní Ìpínlẹ Èkó láti se àkíyèsí òfin wọ̀nyí, kí wọ́n má ba à lu òfin ìbálòpọ̀ ní gbangba ní ọjọ́ iwájú.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fáwọn oníròyìn láàárọ̀…