Home ÀKỌ̀TUN Àwọn Akọ̀ròyìn tàkìtì ìpàkọ́ sí ìpè Fani Kayọde
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 1, 2020

Àwọn Akọ̀ròyìn tàkìtì ìpàkọ́ sí ìpè Fani Kayọde

Àwọn Akọ̀ròyìn tàkìtì ìpàkọ́ sí ìpè Fani Kayọde

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àdúrà gidi tó yẹ kí Ọlọ́gbọ́n èèyàn máa sàmí ẹ̀ wìtìwìtì ni pé ibi tí a ti ń níyì, káláwùràbí ó má jẹ́ á tẹ́.
Àwọn akọròyìn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ náà ti kọ ìpàkọ́ sí ìpàdé àwọn akọ̀ròyìn tí Mínísítà tẹ́lẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Fẹmi Fani Kayọde pé nílù Ìbàdàn.

Àwọn tó ṣe ètò ìpàdé oníròyìn náà ti kọ́kọ́ ríi dájú pé ìwọ̀nba àṣàyàn àwọn akọròyìn ni wọ́n pé, wọ́n sì fi kún un pé ìwọ̀nba àwọn tí wọ́n fi ìwé pè nìkan ló yọjú níbẹ̀.

Lẹ́yìn ò rẹyìn, àtàwọn tí wọ́n fi ìwé pè, àtàwọn tí wọn kò fi ìwé pé ló kọ láti yọjú síbi ìpàdé náà.

Alága NUJ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Demola Babalola náà fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn pinnu láti má bu ọlá fún ìwé ìpè tí FFK ti kọ́kọ́ fi ránṣẹ́ sí ẹgbẹ́ wọn

Èyí kò ṣẹ̀yìn bí àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ akọròyìn ti ṣe pàṣẹ fáwọn akọròyìn pé kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn tó gbọ́dọ̀ dé ibi ibùdó náà.

Ìgbésẹ̀ yìí ń wáyé lórí ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tí Fani Kayọde sọ sí akọròyìn iléeṣẹ́ Ìròyìn Daily Trust ní ìlú Calabar, ní ìpínlẹ̀ Cross Rivers.

Saájú ìgbésẹ̀ yìí náà ni ẹgbẹ́ akọròyìn ní ìpínlẹ̀ Akwa Ibom náà ti gbé ìgbésẹ̀ yìí.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn àgbà sọ pé ìjàngbọ̀n kìí nìka…