Home ÀKỌ̀TUN Aàrẹ pàṣẹ pé kí ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí àwọn tó lu owó Kofi 19 ń póńpó
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - September 1, 2020

Aàrẹ pàṣẹ pé kí ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí àwọn tó lu owó Kofi 19 ń póńpó

Aàrẹ pàṣẹ pé kí ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí àwọn tó lu owó Kofi 19 ń póńpó

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Kenya, Uhuru Kenyatta ti pàṣẹ kí iléeṣẹ́ ètò ìlera ṣe àfihàn gbogbo ìwé tó ní i ṣe pẹ̀lú ohun tí wọ́n rà nípa kíkojú àjàkálẹ̀ àrùn Kofi-19 ní Kenya.

Ààrẹ Uhuru Kenyatta gbé ìgbésẹ̀ yí lẹ́yìn tí ọ̀rọ̀ jẹyọ pé àwọn aláṣẹ kan jí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù dọ́là tó yẹ kí wọ́n fi ra nǹkan èèlò ìtọ́jú àrùn Kofi-19.

Lára àwọn ìwé àṣẹ ìnáwó tó ní kí wọ́n gbé jáde léyìí tí iléeṣẹ́ tó ń pèsè èèlò ìtọ́jú aláìsàn ní Kenya, Kenya Medical Supplies Agency fi ra nǹkan.

Iléeṣẹ́ yìí gan an ni wọ́n ní màgòmágó ti wáyé nípa owó tó yẹ kí wọ́n fi ra nǹkan èèlò ìtọ́jú alárùn Kofi-19.

Lásìkò tó ń bá àwọn Gómìnà ìpínlẹ̀ ṣọ̀rọ̀ ni Ààrẹ Uhuru kéde ọ̀rọ̀ yìí.

Uhuru ni ”Ileeṣẹ ìlera gbọdọ̀ ṣe àfihàn ọ̀nà ìgbówó jáde tí kò lẹ́ja n bákàn nínú jáde láàrin ọgbọ̀n ọjọ́ èyí tí gbogbo èèyan yóó rí lójú òpó ayélujára”

Àwọn aláṣẹ tí wọ́n fi ẹ̀sùn yí kan sọ pé àwọn kò mọwọ́ mẹsẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…