Home ÀKỌ̀TUN Òògùn ìtura dé fún Kofi-19!
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - August 30, 2020

Òògùn ìtura dé fún Kofi-19!

Òògùn ìtura dé fún Kofi-19!

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí ẹkún bá pẹ́ títí dalẹ́, kò sí àníàní, àwọn àgbà gbà pé ayọ̀ ń bọ̀ ní òwúrọ̀ ni . Àsamọ̀ yìí ló ń gbé ìròyìn kan tí ó ń ṣe é lálàyé pé òògùn àrùn Kofi-19 kan tí wọ́n fi àrídájú hàn pé ó ń ṣíṣe ti jáde láti Ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì Oxford èyí tó sì fi hàn pé kò mú ewu dání rárá.

Bákan náà wọ́n jẹ́ kó di mímọ̀ pé ó máa ń tọ àgọ́ ara sọ́nà nípa ohun tó yẹ kó ṣe, kí ara leè jí pépé.

Àyẹ̀wò rẹ̀ tí wọ́n ṣe lára èèyàn ẹgbẹ̀rún kan ó lé mẹ́tàdínlọ́gọ́rin fi hàn pé àbẹrẹ náà gbé àwọn ajagun inú ara dìde tólóyìnbó ń pè ní ‘antibodies’ àti èròjà ara míì fún ìjagun (white blood cell) èyí tó leè dojú ìjà kọ àrùn Kòrónáfairọ̀ọ̀sì.

Àbájáde ìwádìí yìí fihàn pé ìreti gidi wà, amọ ṣa, ó ti yá jù láti mọ̀ bóyá èyí nìkan ti tó láti dájọ́ pé ó ń ṣíṣe láti dá àbò bo ara, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn òògùn àyẹ̀wò míì sì wà lọ́nà.

Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti bèèrè láti ra mílíọ̀nù lọ́nà Ọgọ́rùn òògùn náà báyìí.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…