Home ÀKỌ̀TUN Káyọ̀dé Williams, adigunjalè tó ń fi àyípadà rẹ̀ ran àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ́wọ́
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - August 28, 2020

Káyọ̀dé Williams, adigunjalè tó ń fi àyípadà rẹ̀ ran àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ́wọ́

Káyọ̀dé Williams, adigunjalè tó ń fi àyípadà rẹ̀ ran àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ́wọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwámárídìí sáà ní Adẹ́dàá n ṣe gbogbo nǹkan Rẹ̀ , bẹ́ẹ̀ kò sì wá ku èèyàn tí yóó bií pé kín ló dé tó fi ṣe bẹ́ẹ̀. Àbi, kó sáà tó di àtúnbí, ògbóǹtarìgì ọ̀daràn ni Káyọ̀dé Williams tí orúkọ rẹ̀ ti yípadà sí Bísọ́ọ̀bù Káyọ̀dé Williams báyìí.

Káyọ̀dé Williams ní ìgbé ayé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ gbáà ni kí èèyàn lọ sẹ̀wọ̀n àti kí ó tẹ̀wọ̀ndé, èyí tó sì nílò ìlanilọ́yẹ àkọ̀tun.

“Ó nílò ìkọ́ni, ìdarí, ọ̀rọ̀ pé o gba ẹ̀sìn kọ́ ni eléyìí, Ọlọ́run gbudọ̀ tún un bí, torí èèyàn ṣáà ni mí…”

“Ọgbà ẹ̀wọ̀n Nàìjíríà tó kàn rí bíi pé wọ́n kó ẹranko sí Zoo ni kò jẹ́ kí ayé àwọn ọ̀daràn yí padà”

Ó sọ àṣírí bí àwọn Pásítọ̀ àti Wòlíì ńlá ńlá ṣe máa ń ṣẹ̀rí ìbùkún s’órí ìbọn wọn àti ìfàmì òróró yàn kí wọ́n tó jáde lọ ja olè, bí wọ́n bá sì darí wọ́n á wá fi ìdámẹ́wàá sílẹ̀. Káyọ̀dé ní kìí ṣe pé ìwà àwọn pásítọ̀ wú òun lórí l’òun ṣe fayé òun fún Jésù bí kò ṣe pé Ọlọ́run dìídì gba ẹnu adájọ́ tó pàṣẹ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá fún un ṣọ̀rọ̀ sínú ayé òun.

Wiliams sọ bí ó ṣe pàdé ògbóǹtarìgì adigunjalè Ishola Oyenusi tó gbájúmọ́ nígbà ayé rẹ̀ fún dída ìlú rú.

Ó dárúkọ Ọ̀mọ̀wé Ishola Oyenusi, Babatunde Folorunsho, Baba Koshewọn tó jẹ́ pé ọwọ́ ọlọ́pàá kò kì ń tẹ̀ ẹ́.

Ọmọdé ni Káyọ̀dé nígbà náà ṣùgbọ́n ìtàn bí ẹgbẹ́ àwọn àgbàlagbà ọ̀daràn ṣe fi owó tàn án t’óun náà bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ìbọn , tó sì ń mu igbó jẹ́ ìbànújẹ́ tó dorí àgbà kodò.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …