Home ÀKỌ̀TUN Ọwọ́ tẹ pásítọ̀ tó jábálé ọmọ ìyá méjì
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - August 27, 2020

Ọwọ́ tẹ pásítọ̀ tó jábálé ọmọ ìyá méjì

Ọwọ́ tẹ pásítọ̀ tó jábálé ọmọ ìyá méjì
Láti ọwọ́ Yínká Àlàbí
Ojo gbogbo n’tole, ojo kan pere ni t’olohun. Pasito Nduka Anyanwu ni o n foju wina idajo ni ile ejo to fi ikale si ilu Yaba ni ipinle Eko. Pasito omo odun mejidinlaadota lo fi ogbon gbigba adura jabale arabinrin omo odun metadinlogun ati aburo re omo odun metala.
Agbegbe Oshodi ni isele naa ti sele, nigba ti owo te Pasito, o jewo fun ile-ejo pe ise Esu ni ki adajo jowo siju aanu wo oun nitori pe oun ko ni je ki iru re waye mo.
Agbejoro ijoba je ki o ye Pasito naa pe oun ti o se lodi si ofin abala 137 iwe iwa odaran orileede yii ati wi pe ijiya nla lo wa fun eni to ba fipa ba omo ti koo tii le da duro ni orileede yii lo. Ni eyi to tumo si omo ti ko ba tii pe odun mejidinlogun.
Onidajo A. Adebayo ni ki Pasito naa si wa ni ahamo titi ti idajo fi maa waye ni ojo keedogun osu kesan-an to n bo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…