Home ÀKỌ̀TUN Ọlọ́pàá tí apànìyàn Ìbàdàn sá mọ́ lọ́wọ́ ti wọ gàù
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - August 27, 2020

Ọlọ́pàá tí apànìyàn Ìbàdàn sá mọ́ lọ́wọ́ ti wọ gàù

Ọlọ́pàá tí apànìyàn Ìbàdàn sá mọ́ lọ́wọ́ ti wọ gàù
Láti ọwọ́ Yínká Àlàbí
Sunday Shodipe ni omo odun mokandinlogun ni agbegbe Akinyele ni ilu Ibadan ti o je ogbologbo apaniyan ti foto ati oruko re wa kaakiri inu iroyin lati ose to koja. Apaniyan yii ni o kan dede n pa awon eniyan kaakiri ilu Ibadan ki owo awon olopaa to tee.
Ito ni apaniyan yii ni oun fe lo to ni nnkan bii aago meje ale ki o to sa mo awon olopaa lowo. Leyin eyi ni o tun lo se iku pa elomiran ni ilu Ibadan kan naa. Shodipe je ki o ye awon olopaa pe babalawo to wa leyin oun lo je ki ise naa rorun fun oun bi o tile je pe ko jewo ise ibi ti oun ati babalawo naa n fi eya ara tabi eje eniyan se ti won fi yan iru ise buruku bee laayo.
Komisona olopaa ni ipinle Oyo, Ogbeni Joel Nwachukwu Enwonwu fi asiko yii naa ro awa oniroyin lati mo ohun ti a maa ko sile fun awon ara ilu lati ka. O ni o ye ki oniroyin gidi maa wadii ohun gbogbo daju ki won to maa ko nnkan sile. Bee naa lo gba awon ara ilu naa nimoran pe iroyin ori ero ayelujara naa ko to lati gbagbo. O ni orisiirisii ikokuko ni o wa lori ero ayeleujara ti opo eniyan si n gbaa gbo. O wa dabi igba ti awon olopaa lowo si bi odaran naa se jade ni ahamo ki owo to tun tee leyin ise ibi miiran.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…