Home ÀKỌ̀TUN Akínwùmí Adéṣínà di adarí Báńkì AFDB lẹ́ẹ̀kejì
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - August 27, 2020

Akínwùmí Adéṣínà di adarí Báńkì AFDB lẹ́ẹ̀kejì

Akínwùmí Adéṣínà di adarí Báńkì AFDB lẹ́ẹ̀kejì

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àkọsílẹ̀ ẹ̀dá láyé kò ní tà ṣé, torí pé omi tí ẹ̀dá yóó mu kò ní sàn kọjá ẹ̀ ní dúníyàn. Àwọn àsamọ̀ ọ̀rọ̀ yìí ló díá fún bí wọ́n ti tún Akínwùmí Adéṣínà yàn gẹ́gẹ́ bíi adarí Báńkì Ìdàgbàsókè ilẹ̀ Áfírìkà, AFDB.

Òun ni yóó máa tukọ̀ ìdarí báńkì náà fún sáà ọlọ́dún márùn ún míràn, lẹ́yìn tí ìwádìí ti fihàn pé kò sí kọ́nú n kọ́họ kankan nínú sáà ìṣèjọba rẹ̀ àkọ́kọ́.

Akínwùmí Adéṣínà ti jẹ Mínísítà ètò ọ̀gbìn fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà rí. Àtúnyàn rẹ̀ kàn jẹ́ kó má dà bíi pé wọn kò tẹ̀lé Ìlànà ní torí òun nìkan ṣoṣo náà ni olùdíje tó wà níbi ètò ìdìbò náà, èyí tó wáyé lórí ayélujára nibi ipade banki naa tó wáyé lọ́jọ́bọ.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ tó sọ láti pè fún kí wọ́n dìbò yàn án fún sáà kejì, Adéṣínà ní òun ń lo ohun gbogbo tí òun ní láti sin ilẹ̀ Áfírìkà láì lẹ́ja n bákàn nínú.

Ẹni ọgọ́ta ọdún ni Akínwùmí Adéṣínà .

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …