Home ÀKỌ̀TUN Òṣìṣẹ́ Task Force àtoní Dáńfó kọlura l’Ógùn, ọ̀rọ̀ di pẹ́ǹtúká
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - August 26, 2020

Òṣìṣẹ́ Task Force àtoní Dáńfó kọlura l’Ógùn, ọ̀rọ̀ di pẹ́ǹtúká

Òṣìṣẹ́ Task Force àtoní Dáńfó kọlura l’Ógùn, ọ̀rọ̀ di pẹ́ǹtúká

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn awakọ̀ Dáńfó kan lójú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí Abeokuta daṣẹ́ sílẹ̀ lọ́sàn án Ọjọ́rú èyí tó fa ọ̀pọ̀ ìdààmú fún àwọn arìnrìnàjò lójú ọ̀nà náà.

Ìròyìn ní àwọn òṣìṣẹ́ Ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá tó ń rí sí ìgbòkègbodò ojú pópó ní ìpínlẹ̀ Èkó, Task Force, ya bo agbègbè Abúlé-Ẹ̀gbá àti Ìjàyè láti ṣiṣẹ́ wọn, ṣùgbọ́n àwọn jàǹdùkú dojú ìjà kọ àwọn òṣìṣé ọ̀hún pẹ̀lú àwọn ohun ìjà olóró.

Wọ́n ní àwọn òṣìṣẹ́ task Force yìnbọn fún ọ̀kan lára àwọn jàǹdùkú ọ̀hún tí wọ́n jẹ́ awakọ̀, èyí tó dá wàhálà sílẹ̀.

Ìjà náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn èrò ọkọ̀ àtàwọn oníṣòwò tó wà lágbègbè náà sá àsálà fún ẹ̀mí wọn.

Alága Ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá ọ̀hún, Yinka Egbeyemi sọ fún akọròyìn pé, òótọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, ṣùgbọ́n àwọn òṣìṣẹ́ òun kò yìnbọn pa ẹnikẹ́ni lára àwọn jàǹdùkú náà.
Ó ní “Àwọn jàǹdùkú kan kó ara wọn jọ nínú ọkọ̀ akérò, wọ́n sì kọlu àwọn òṣìṣẹ́ wa, àwa náà sì kọlù wọ́n.”

“A ti fi páńpẹ́ òfin mú àwọn jàǹdùkú ọ̀hún, wọ́n sì ti wà ní àhámọ́ wa.”

Ìṣẹ̀lẹ̀ náà mú kí ogunlọ́gọ̀ awọn tàwọn tó yẹ kó wọ ọkọ̀ fẹsẹ̀ rìn lẹ́yìn tí àwọn Dáńfó kọṣẹ́ lẹ́yìn ìsẹ̀lẹ̀ náà.

Ọ̀kan lára àwọn èèyàn náà, Lanre Obabiyi sọ fún àwọn akọròyìn pé, ẹ̀rù ba òun nígbà tí òun gbọ́ ìró ìbọn, tí òun sì sá lọ forípamọ́ nínú báńkì kan tó wà lágbègbè ọ̀hún.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…