Home ÀKỌ̀TUN A ti mú afurasí tó ń jẹ igbẹ níbàdàn–Ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - August 23, 2020

A ti mú afurasí tó ń jẹ igbẹ níbàdàn–Ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá

A ti mú afurasí tó ń jẹ igbẹ níbàdàn–Ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ayé ń lọ sópin, ohun tétí ò fẹ́ ẹ̀ gbọ́ rí lojú ń rí báyìí o.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹwu lóri ọkùnrin kan tí orukọ́ rẹ̀ ń jẹ́ Emmanuel Egbu tí wọ́n ní ó ń fi ìgbẹ́ jẹ búrẹ́dì ní orí àkìntàn nílùú Ìbàdàn.

Wọ́n ní àwọn kan ní àdúgbò Sáńgo ló ké gbàjarè tí wọ́n sì fi ọ̀rọ̀ náà tó ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá àgbègbè náà léti ki àwọn ará àdúgbò tó ṣe ìdájọ́ fún un láti ọwọ́ ara wọ́n.

Agbẹnusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá nípìnlẹ̀ Ọ̀yọ́, Olugbenga Fadeyi ṣàlàye fún akọròyìn pé, ní kété tí wọ́n mú ọkùnrin náà ni wọ́n ti gba ọ̀rọ̀ sílẹ̀ lẹ́nu rẹ̀ ti wọ́n sì gba onírúurú ìgbẹ́ ti wọ́n ri lọ́wọ́ rẹ̀ láti gbé e lọ fún àyẹ̀wò.

Yàtọ̀ sí ìròyìn kan tó sọ pé gbajúgbajà olùtajà àwọn èròjà àṣara àti irun lóge ni ọkùnrin náà tó sì ni ṣọ́ọ̀bù ńlá ńlá ni àdúgbò Sáńgo nílùú Ìbàdàn àti pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ra ilé ńlá kan ni, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní ọjọ́ Sátidé, ọjọ́ kejìlélógún ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, àjọ ọlọ́pàá sì ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ náà ni.

Fadeyi ní òun kò le fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ àfi tí ìwádìí bá parí ṣùgbọ́n ní òótọ́ ni àwọn bá ìgbẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, tí àwọn sì ti kó wọ́n lọ fún àwọn àyẹwò tó yẹ.

Ẹ̀wẹ̀, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ọkùnrin náà wà ní àgọ́ ọlọ́pàá agbègbè Sáńgo nílùú Ìbàdàn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …