Home ÀKỌ̀TUN Bishop Oyedepo ní láti tẹ̀lé òfin tàbí kí ó dá orílèèdè tirẹ̀ sílẹ̀ – Iléesẹ́ Ààrẹ
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - August 19, 2020

Bishop Oyedepo ní láti tẹ̀lé òfin tàbí kí ó dá orílèèdè tirẹ̀ sílẹ̀ – Iléesẹ́ Ààrẹ

Oludasile ile ijosinLiving Faith Church Worldwide, Bishop David Oyedepo lo ti n gbe peregi kana pelu ijoba apapo lati bii odun meloo kan seyin.
Ofin lori owo ori ati amojuto awon ile-ise ati awon ile-ijosin ti ajo Company and Allied Matters Acts (CAMA) maa samojuto gege bi ijoba apapo se sagbekale re lo fa gbonmi-sii-omi- o too ti ote yii.
Bishop Oyedepo ni eyinju Olorun ni ile-ijosin, ko letoo sii ki enikeni fowo kan an. O ni oro ile-ijosin da bi igba ti alagata kan ba fowo kan iyawo wa. O ni eleyii maa n fa ibinu gidi. O ni bee gege ni oro ile-ijosin ri si Olorun. O ni ijoba ko letoo lati maa da si amojuto tabi oro nipa owo ori ni ile Olorun.
Arabinrin Lauretta Onochie ti o je okan ninu awon olubani-damoran lori iroyin ni ileese Aare lo da Bishop Oyedepo lohun lori ero ayelujara Twitter pe ko letoo bi Alagba ijo yii se n benu ate lu ofin ijoba apapo. Arabinrin yii ni ile ijosin Bishop Oyedepo kan naa to wa ni orileede London n san owo ori re deedee, bee lo si n tele gbogbo ofin ti ijoba orileede naa gbe kale. Arabinrin yii ni bawo lo se wa je ti ijoba Naijiria ko tii ni soro ti Alagba yii ti maa koo danu?
Onochie ni eyi ku die kaa to, o ni ko si orileede ti ile-ijosin tabi enikan ti ga ju ofin lo. O ni ti Alagba Oyedepo ba si ti mo pe oun ko ni tele ofin Naijiria, ki o yara lo da orileede tire sile ki o si maa sofin bi o ba se wuu.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…