Ìrìnna ọkọ́ òfúrufú s’ílẹ̀ òkèèrè yóò bẹ̀rẹ̀ padà– Ìjọba àpapọ̀
Ìrìnna ọkọ́ òfúrufú s’ílẹ̀ òkèèrè yóò bẹ̀rẹ̀ padà– Ìjọba àpapọ̀
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti kéde pé ìrìnnà ọkọ̀ òfurufú sí ilẹ̀ òkèèrè yóó bẹ̀rẹ̀ padà ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹjọ ọdún 2020.
Mínísítà fétò ìrìnnà òfurufú, Hadi Sirika ló fi èyí síta lójú òpó Sítágíràmù àti abẹ́yefò Twitter rẹ̀.
Ó ní ìgbésẹ̀ yìí yóó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú pápákọ̀ òfurufú tó wà ní ìlú Èkó àti Àbújá.
Bákan náà ló fi kún un pe gbogbo ìgbésẹ̀ àti ìlànà tó bá yẹ fún ìdápadà ìrìnàjò sílẹ̀ òkèèrè náà yóó bọ́ sí òjútáyé láìpẹ́
Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo
Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …