Home ÀKỌ̀TUN Ìgbìmọ̀ olùgbẹ́jọ́ yẹ àga mọ́ Gómìnà Bayelsa nídìí
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - August 17, 2020

Ìgbìmọ̀ olùgbẹ́jọ́ yẹ àga mọ́ Gómìnà Bayelsa nídìí

Ìgbìmọ̀ olùgbẹ́jọ́ yẹ àga mọ́ Gómìnà Bayelsa nídìí

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní àtòrì layé, tó bá lò síwájú, ó tún lè lò sẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ rí bí Ilé ẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò Gómìnà nípìńlẹ̀ bayelsa ti wọ́gilé ìbò tó gbé Gómìnà Douye Diri àti ìgbákejì rẹ̀, Lawrence Ewhrudjakpo wọlé.

Nínú ìdájọ́ tí adájọ́ Yunusa Musa gbé kalẹ̀ lórí ẹ̀hónú ìbò Gómìnà tí ẹgbẹ́ òṣèlú ANDP gbé wá síwájú rẹ̀, ìgbìmọ̀ olùgbẹ́jọ́ ẹ̀hónú ìbò náà ni àjọ elétò ìdìbò ló yọ orúkọ olùdíje ìbò Gómìnà fún ẹgbẹ́ òṣèlú náà lọ́nà àìtọ́.
Ìgbìmọ olùgbẹ́jọ́ náà wá pàṣẹ fún àjọ INEC láti tún ètò ìdìbò Gómìnà míì se nípìńlẹ̀ Bayelsa láàrin àádọ́sàn ọjọ́ péré.

Bákan náà ló tún fikún-un pé, àjọ elétò ìdìbò gbọdọ̀ fi olùpẹ̀jọ́ náà, èyiùn ẹgbẹ́ òṣèlú ANDP sínú ètò ìdìbò tuntun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn àgbà sọ pé ìjàngbọ̀n kìí nìka…