Home ÀKỌ̀TUN Ogúndípẹ̀ gbé Fásitì Unilag ló sí iléẹjọ́
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - August 14, 2020

Ogúndípẹ̀ gbé Fásitì Unilag ló sí iléẹjọ́

Ogúndípẹ̀ gbé Fásitì Unilag ló sí iléẹjọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀gá Àgbà Ilé ẹ̀kọ́ Fásitì ìpínlẹ̀ Èkó tí wọ́n yọ nípò, Olúwatóyìn Ogúndípẹ̀ ti gba iléẹjọ́ lọ lẹ́yìn tí Àjọ amúṣẹ́yá Fásitì náà yọ ọ́ kúrò nípò.

Àsìkò ìpàdé àwọn àjọ amúṣẹ́yá tí wọ́n ṣe ní iléeṣẹ́ National Universities Commission ní ìlú Àbújá ni wọ́n ti yọ Ọ̀jọ̀gbọ́n Ogúndípẹ̀ nípò gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá àgbà Fásitì ìlú Èkó.

Níbáyìí, Ọjọ́gbọn náà ti gba agbẹjọ́rò àgbà kan ní Nàìjíríà, Mike Ozekhome láti lọ ṣojú rẹ̀ ní iléẹjọ́.

Nínú àtẹjáde tí Ogúndípẹ̀ kọ sí Ozekhome, Ó ní wọ́n yọ òun láì tẹ̀lé ìlànà òtítọ́ àti òdodo tó yẹ kí wọ́n tẹ̀lé láti yọ òun kúrò ní ipò.

Ọjọ́gbọn Ogúndípẹ̀ ní òun ní àtìlẹ́yìn àwọn òṣìṣẹ́ àti olùkọ́ Fásitì náà, nítorí wí pé ọ̀nà tí wọ́n gbà fi yọ òun tako òfin tó de Fásitì lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ozekhome ní ìdìtẹ̀mọ́ni ni ìpàdé pàjáwìrì tí wọ́n pè láti yọ Ogúndípẹ̀ kúrò nípò.

Bákan náà ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Olúwatóyìn Ogúndípẹ̀ ṣaájú àwọn tó ń fẹ̀hónú hàn lórí bí wọ́n ṣe dédé yọọ́ kúò nípò.

Ogúndípẹ̀ ni ó farahàn pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ olùkọ́ NASU, SSANU àti ASUU níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìfẹ̀hónúhàn láti inú ọgbà Fásitì náà títí dé ẹnu àbáwọlé ilé ẹ̀kọ́ gíga náà.

Lásìkò tí Ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ náà tí wọ́n yọ nípò ń ṣọ̀rọ̀, ó ní ọgbọ̀n ọdún nìyí tí òun ti ń sisẹ́ ní Iléẹ̀kọ́ náà ní ipò kan tàbí òmíràn, nítorí náà wọn kò lè dédé yọ òun bíi jìgá.

Bákan náà ni Alága ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ Fásitì ti ìpínlẹ̀ Èkó, Dókítà Délé Ashiru ní àwọn tako bí wọ́n ṣe yọ Ọ̀jọ̀gbọ́n Ogúndípẹ̀ nípò, tí àwọn sì fi ìgboyà tẹ̀le gẹ́gẹ́ bí adarí wọn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…