Home ÀKỌ̀TUN Wọ́n dájọ́ ikú fún Baba 61 tó fipá b’ọ́mọdé kan lò pọ̀ ní Kano
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - August 13, 2020

Wọ́n dájọ́ ikú fún Baba 61 tó fipá b’ọ́mọdé kan lò pọ̀ ní Kano

Wọ́n dájọ́ ikú fún Baba 61 tó fipá b’ọ́mọdé kan lò pọ̀ ní Kano

Fẹ́mi Akínṣọlá

Iléẹjọ́ Sharia kan ní Kano ti ní kí wọ́n lọ sọ̀kò pa bàbá ẹni ọdún mọ́kanlélọ́gọ́ta kan.

Adájọ́ Ibrahim Sarki Yola ni bàbá náà jẹ̀bi ẹ̀sùn fífi ipá bá ọmọ ọdún méjìlá kan lò pọ̀.

Bàbá náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mati Audu ni ìròyìn sọ pé ó wá láti ìjọba ìbílẹ̀ Tsanyawa ní ìpínlẹ̀ Kano.

Agbẹnusọ ilé ẹjọ́, Sharia ní ìpińlẹ̀ Kano, ni ilé ẹjọ́ náà ri pé lẹ́yìn gbogbo ẹ̀ri to wà níwájú rẹ̀, ọkùnrin náà jẹ̀bi ẹ̀sùn ti wọ́n fi kàn.

O ní ó fipa bá ọmọ ọdún méjìlá lòpọ̀ ni abúlé Farsa ní ọdún 2019.

Bótilẹ̀ jẹ́ pé ìrú ìdájọ́ lórí ẹ̀ṣùn ìfipábanilòpọ̀ kìí sábà wáyé, sùgbọ́n ọkùnrin náà tó ní ìyàwó nílé ni wọ́n ti ní ó jẹ̀bi ikú àti pé wọ́n ní láti sọ ọ́ lókùúta pa ni gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin Sharia lórí irú ìwà bẹ́ẹ̀.

Ẹ̀wẹ̀, agbẹnusọ náà ní, bàbá náà ní ẹ̀tọ́ láti lọ sí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ọ̀rọ̀ náà láàrín ọgbọ̀n ọjọ́.

Èyí ni ìdájọ ikú ẹlẹ́keejì tí ilé ẹjọ́ Sharia yóò dá láàrín ọ̀sẹ̀ kan ní ìpińlẹ̀ Kano

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …