Home ÀKỌ̀TUN Wo ń tó rọ̀ mọ́ òfin Sharia kó o tó lù ú
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - August 13, 2020

Wo ń tó rọ̀ mọ́ òfin Sharia kó o tó lù ú

Wo ń tó rọ̀ mọ́ òfin Sharia kó o tó lù ú

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé ìdálùú nísèlú,wọ̀fún ǹtẹ́lọ́rùn . Bẹ́ẹ̀ Ìlú tí kò sófin ẹ̀sẹ̀ kò sí níbẹ̀.
Ìdí rèé tí a fi ni kí a tan ìmọlẹ̀ sí àwọn ǹkan ti o yẹ kí ẹ mọ̀ nípa òfín Sharia.

Ní ọdún 1999 ni òfin Sharia bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà tí gómìnà ìpińlẹ̀ Zamfara nígbà náà lọ́hùún, Ahmed Sanni Yerima pè fún lílo òfin Sharia láwọn ìpińlẹ̀.

Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di ọdún 2000, àwọn ìpínlẹ méjìlá ní ìhà Àríwá ló ti darapọ̀ mọ́ ètò ọ̀hún, bákan náà ni wọ́n ṣe àfikún láti maa fi òfin Sharia dá ẹjọ́ tó bá níṣe pẹ̀lú ìwà ọ̀daràn.

Láti ìgbà yìí sì ni ọ̀pọ̀ àwọn égbẹ́ ajàfẹ́tọ́ ọmọnìyàn ti ń rọ Ìjọba láti dá sí ìgbésẹ̀ àwọn tó ṣe àgbékalẹ̀ yìí nítorí ní ọ̀pọ̀ ìgbà ní ìdájọ́ Sharia máa ń tẹ òfin ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú mọ́lẹ̀.

Ìpínlẹ̀ méjìla tó di òpó ìhà aárèwá mú ní wọ́n ti ń lo òfin Sharia, àwọn musùlùmí tó sì wà ní àwọn ìpínlẹ̀ yìí nìkan ni òfin Sharia le báwí.Báwo ni wọ́n ṣe ń lo òfin Sharia?Sáájú àsìkò yìí, ẹ̀sẹ̀ tó bá níṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ara ẹni tí a sì gbé ẹjọ́ náà wá sọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ Islam,ibẹ̀ nìkan ní wọ́n ń lo Sharia fún.

Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bíi kí ènìyàn ṣe àgbèrè (Zina), èyí túmọ̀ sí pé tí wọ́n bá ká ọkùnrin tàbí obìnrin mọ́ níbi ìbálòpọ̀ tí kìí sì ṣe pẹ̀lú( ẹlẹ́tọ̀ọ́ rẹ̀) ọkọ tàbi aya wọ́n.

Bákan náà ni bí ènìyàn bá mutí tàbí jalè, ìdájọ́ Sharia ni wọ́n yóò fi ṣèdájọ́ fún irú ẹni bẹ́ẹ̀.

Bákan náà àwọn ìjìyà tí òfin Sharia mú dání lé jẹ́ sísọ ènìyàn ní òkúta pa.

Wọ́n máa ń lo òfin Sharia láti sàmójútó ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó àti ogún pínpín láàrín àwọn Mùsùlùmí.

Kínni ìpílẹ̀ òfin Sharia?

•Kùránì

•Súnnà (ìyẹn ojúlówó hàdíìtì)

•Qiyas (Èrò pípé àwọn onímọ̀)

•Ijma ( èyí ni ìfẹnukò èròngbà àwọn onímọ̀ òfin )

•Àwọn ilé ẹkọ́ ìmọ̀ òfin bi Hanafi, Mailki, Shafi’i Hanbali àti Jafari, àwọn yìí ni wọ́n ń ṣètò bí wọ́n ṣe mú àwọn ìlànà tí wọ́n fi ń lo òfin Sharia jáde nínú Kùránì

•Mu amalat ( ìbáṣepọ̀ àwùjọ

•ibadat (etutu)

Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe sọ síwájú, Ìpínlẹ̀ méjìlá ni Sharia tí ń ṣiṣẹ́ ni Nàìjíríà, àwọn musùlùmí nìkàn ní wọ́n lè ṣe ìdájọ́ wọ́n níbẹ̀.

Àṣà Sharia ní ilé ẹjọ́ kòtẹmilọ́rùn tirẹ̀, tí wọ́n si máa ń gbọ́ ẹjọ́ tó níṣe pẹ̀lú ẹsìn, ìwà ọ̀daràn àti láàrìn àwọn mùsùlùmí síra wọn.

Bákan náà ni ẹni tí wọ́n bá dá lẹ́jọ́ ní ilé ẹjọ́ Sharia lè pé ẹjọ́ kòtẹmilọ́run tàbí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní àwọn ilé ẹjọ́ ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Adájọ́ ilé ẹjọ́ Sharia tí wọ́n ń pè ní Alkali máa ń ní ẹ̀kọ́ ìmọ̀ Islam àti ti ìgbàlódé.

Ẹjọ́ tó bá pa mùsùlùmí àti ẹni tí kìí ṣe mùsùlùmí pọ̀, mùsùlùmí náà ní àṣẹ láti sọ ibi tí ó fẹ́ kí ìgbẹ́jọ́ náà ti wáyé.

Àwọn ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ Sharia máa ń ṣe ni Fífún ènìyàn lẹ́gba, Gígé apá tàbí ẹsẹ̀ ènìyàn, ìdájọ́ ikú tàbí kí wọ́n sọ ènìyàn lókùúta pa.Gbogbo ìdájọ́ dá lórí irú ẹ̀sẹ̀ tí ènìyàn bá ṣẹ̀.
À ò níí dẹni ayé ń ṣọ lókò bí adárípọ́n.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …