Home ÀKỌ̀TUN Covid-19- kó̩ ló pa Babatunde Oke
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - August 12, 2020

Covid-19- kó̩ ló pa Babatunde Oke

Covid-19 ko lo pa Babatunde Oke
Owuro oni ni won kede iku Alaga ijoba ibile Onigbongbo, Ogbeni Babatunde Oke.
Gbogbo iroyin to gbee ni ajakale arun coronavirus lo paa. Won ni baba naa se aisan ranpe ni nnkan bii ose meta seyin sugbon ti ara ti ya.
Won ni alaga yii se odun ileya pelu awon ololufe ati ore pelu ojulumo ni asiko odun naa.
Asiko yii gan-an ni awon olutele oloogbe naa ni ategun tun raaye wo ara re. Won ni bi aisan naa se wo baba naa mole niyen. Eyi mu ki won sare gbee lo si ile iwosan aladaani Kan.
Ile-iwosan naa ni alaga naa ti gbemi mi ti o si je Olorun nipe.
Awon olutele Alaga naa ni won ba IROYIN OWURO soro, won ni covid-19 ko lo pa baba naa. Won ni awon si wa nibi igbokusi ni Yaba lati se oku naa lojo fun igba die.
Awon alaba-sise oloogbe naa ni ti o ba je covid-19 lo pa baba naa, ile-iwosan ko ni fi oku naa sile bee ni won ko si nii gba ki awon toju iru oku naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …