Home ÀKỌ̀TUN Sé Covid-19 wà ní Nàìjíríà?
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - August 11, 2020

Sé Covid-19 wà ní Nàìjíríà?

A ku ọjọ mẹta ẹyin alarojinlẹ. A si ku u lasigbo coronavirus to gbaye kan. Ibeere ti ọpọ ọmọ Naijiria n beere ni mo fi se akọle arojinlẹ wa lonii.
Covid-19 ni arun to fara pẹ akọ iba. Ajakalẹ arun ni, o si ti wa lagbaye lati bii osu kejila ọdun 2019. O wọ orileede Naijiria ni ipari osu keji ọdun yii. Ni igba ti o di osu kẹta, ibẹru-bojo mu ijọba apapọ, wọn ti ile-iwe, wọn ti papakọ ofurufu ati awọn ile-isẹ ni orileede yii.
Osẹ meji akọkọ sẹru ba gbogbo ọmọ orileede yii, ofin konile-o-gbele gba ilu kan ni ilu Eko, Abuja ati ipinlẹ Ogun. Ọsẹ ati osu miiran tẹle eleyii bi o tilẹ je pe ko mulẹ bii ti alakọkọ.
Ajakalẹ arun yii bẹrẹ si ni pa awọn to lorukọ niluu, o n pa kukuru, o n pa giga, arun yii ko mọ ọkunrin bẹẹ ni ko ya obinrin sọtọ. Arun yii ko naani ẹsin tabi ẹya Kankan.
Ni igba ti o ya, ọpọ wa rii pe arun naa kii se ọjọ iku. Bi o se n mu eniyan to, iwosan si n de ba ida meji ninu mẹta ti o n mu. Ijọba apapọ se ohun to dara nipa yiyan ajọ alamojuto arun naa (PTF ati NDDC). Ogbeni Boss Mutapha ni alaga ajọ naa. Alagba yii ni akọwe agba fun ijọba apapọ, ninu ajọ naa ni a ti ri minisita eto iroyin ati asa, ti eto ilera, ti eto ẹkọ, ti eto ilẹ okeere ati awọn eniyan jankan-jankan lawujọ. Ojoojumọ ni wọn si n fun awa oniroyin ni abọ igbiyanju wọn ki gbogbo ọmọ Naijiria le mọ ibi ti isẹ de duro.
Ijọba seto owo ati ounjẹ iranwọ fun awọn ara ilu, awọn ileeesẹ aladaani naa rọjo biliọnu naira fun ijọba ki ebi maa ba lu wa pa ni orileede yii.
Owo yii ni o dabi eni to da eto naa ru mọ awọn eleto lọwọ. Iroyin bẹrẹ si ni jade pe awọn ile-iwosan ti sọọ di jẹun-jẹun, wọn ni ti ẹni to ba fẹsẹ kọ ba de ile iwosan, wọn a fun un ni nọmba Covid-19, ẹni ti eegun gun lọrun, wọn a fun un ni nọmba covid-19, ẹni to fe gbe oku kọja ni opopona, afi ki eniyan oku tọwọ bọ’we pe covid-19 lo paa. Ija rẹpẹtẹ ni ile iwosan nipa covid-19 ati bẹẹ bẹẹ lọ. Eyi jẹ ki ọpọ eniyan gba pe ko si ohun to n jẹ covid-19 ni Naijiria. Awọn kan ni arun olowo ni, awọn kan ni iba lasan ni ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ẹyin alarojinlẹ IROYIN OWURỌ, ajakalẹ yii wa loootọ, awọn eniyan buruku lo ba eniyan rere jẹ. Ohun ti awọn kan maa jẹ ni ko jẹ ki wọn gbọn. Gbogbo owo ati ounjẹ ti ijọba ni ki awọn alagbara kan pin ni wọn gbẹsẹ le. Eyi mu ki awọn ọmọ Naijiria bẹ sita lati wa ounjẹ oojọ wọn lọ.
“Onile ni lọwọ, alejo di sẹru” ni ọrọ Naijiria. Ilu bii orileede yii ko si laye mọ. O fẹrẹ ma si ẹka isẹ ni ilu yii ti ijọba ko tii ya owo rogun-rogun si sugbọn okoowo ni awọn kan n fi se.
Ẹyin alarojinlẹ, ẹ jẹ ki a maa sọra daadaa. Ni asiko yii, ẹ jẹ ki nnkan gbigbona pọ ninu ohun jijẹ ati mimu wa, ki awọn ounjẹ bii jinja, orogbo, ewuro ati awọn nnkan miiran ti awọn onisegun ba ni ki a maa lo. Covid-19 wa, ko si ẹni ti ko le mu. Ẹ sọra o.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…