Home ÀKỌ̀TUN Ilé ìjọ́sìn bẹ̀rẹ̀ ìsìn lọ́jọ́ jímọ̀ àti sọ́ńdè
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - August 11, 2020

Ilé ìjọ́sìn bẹ̀rẹ̀ ìsìn lọ́jọ́ jímọ̀ àti sọ́ńdè

Mosalasi jimo to wa ni Alausa ni ilu Ikeja ati awon mosalasi to ku bere irun jimo kiki ni ojo keje, osu kejo odun yii.
Mosalasi to ye ko gba egberun meji eniyan wa di ohun ti eniyan eedegbeta pere kirun nibe. Eyi ri bee gege bi alaale ijoba apapo nitori ajakale arun covid-19 to gbode kan.
Lati enu Mosalasi naa ni won ti n se ayewo awon ti ara won ba gbona ju, aaye ifowo naa wa lo jantirere.
Erin ko yato to fi de ilu oyinbo, eni to ba kawo leri, ekun lo n su. Bakan lomo sori ni awon Soosi ti o je ile ijosin kaakiri ipinle Eko. Ida ogbon ninu ogorun-un ni won gba laaye lati josin leekan naa.
Gbogbo awon ile ijosin yii ni ijoba ipinle Eko ti fi oogun to le pa eyikeyi kokoro to ba wa ni awon ile ijosin naa. Eyi lo mu ki okan awon eniyan bale lati le josin ni awon ile ijosin naa.
Awon Mosalasi ati awon Soosi yii gbiyanju lati tele gbogbo ofin ijoba apapo, won ko je ki awon agbalagba ti ojo ori won ti wo ogota odun ati awon omo weewe wo Soosi tabi Mosalasi josin.
Pelu gbogbo igbiyanju ati ayewo yii, eru si tun n ba awon eniyan kan. Won ni awon ko le fi emi ara awon wewu. Awon ko ti le maa lo si ile ijosin kankan bayii. Won ni awon si maa ni suuru bii ose meji si meta ki awon to le maa darapo pelu awon ara ita josin.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn àgbà sọ pé ìjàngbọ̀n kìí nìka…