Home ÀKỌ̀TUN Búrùjí Kashamu tẹ́rí gbaṣọ
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - August 8, 2020

Búrùjí Kashamu tẹ́rí gbaṣọ

Búrùjí Kashamu tẹ́rí gbaṣọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé ikú kò dọ́jọ́, bẹ́ẹ̀ ni àrùn kò dósù àti pé, àrùn la rí wò, kò sẹ́ni tó rí ti ọlọ́jọ́ ṣe.
Sẹ́nétọ̀ tó ń sójú ẹkùn Ogun East, Buruji Kasahamu ti jẹ́ Ọlọ́run nípè.

Gẹ́gẹ́ bí ìlúmọ̀ọ́ka olóṣèlú Ben Murray-Bruce ṣe sọ, Ó ní ó kú sí ilé ìwòsàn First Cardilogy Consultant ní ìlú Èkó.

Bruce ni ọ̀rẹ́ wọlé wọ̀de ni òun àti Kasahamu kó tó jẹ́ Ọlọ́run nípè.

Sááju àsìkò yìí ni ìròyìn ti kan pé Kasahamu wà ní ẹsẹ̀ kan ayé, ẹsẹ̀ kan ọrún nítorí àwọn àrùn míràn tí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì bá lára bàbá náà.
Kìí ṣe ògbóǹtarìgì olóṣèlú yìí nìkan ló máa kọ́kọ́ kú ikú Kofi-19, àwọn mìíràn náà tó jẹ́ èèkàn ìlú káàkiri ilẹ̀ yìí náà tí bá a rìn.Díẹ lára wọn ni Abba KyariOlorì òṣìṣẹ́ t’ẹ́lẹ̀ ní lọ́ọ́fìsì Ààrẹ(Àbújá),
Adebayo Sikiru Osinowo( Èkó),Sul
man Adamu(Nasarawa ),Shuaibu Danlami( Gombe),Wahab Adegbenro( Òǹdó),Aminu Adisa Logun (Kwara),Tunde Buraimoh (Èkó)

Nǹkan bí ogójì ọjọ́ sẹ́yìn ní Gómìnà àná Abíọ́lá Ajímọ̀bi náà papòdà látàrí àrùn ajániláyà pàtì méèmí ẹni lọ ọ̀hún tó ń fi gbogbo àgbáláayé nàkànnàkàn.
Kóówá àwọn wọ̀nyí tí wáyé wọ́n ti lọ.
Òní ní yóó ròyìn ọ̀la, ìtàn ni yóó ròyìn àtubọ̀tán èèyàn.
Ìròyìn Òwúrọ̀ gbàá ládúrà pé kí Ọlọ́run dúró tí ẹbí àwọn èèyàn náà tó ti gbékuru gàjà, káwa náà ó má lùgbàdi àrùn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fáwọn oníròyìn láàárọ̀…