Home ÀKỌ̀TUN Ilé ìjọsìn yìí gbàgbọ́ nínú ọtí àmupara ṣaájú bíbá Ọlọ́run ṣọ̀rọ̀
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - August 7, 2020

Ilé ìjọsìn yìí gbàgbọ́ nínú ọtí àmupara ṣaájú bíbá Ọlọ́run ṣọ̀rọ̀

Ilé ìjọsìn yìí gbàgbọ́ nínú ọtí àmupara ṣaájú bíbá Ọlọ́run ṣọ̀rọ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Orílẹ̀-èdè South Africa ti bẹ̀rẹ̀ ìfilọ́lẹ̀ òfin tó de ọtí títà lásìkò Kofi -19 fún ìgbà kejì.

Ìjọba South Africa ṣe àgbékalẹ òfin tó de káràkátà ọtí líle láti mú àdínkù bá iye àwọn èèyàn tó ń lọ sí ilé ìwòsàn.

Àgbékalẹ ìlànà yí ni ìpalára fún àwọn ará ìlú lọ́nà oríṣìríṣi paàpá àwọn Ilé ìtajà ọtí àti Ilé oúnjẹ.

Àmọ́ ṣá ọ̀rọ̀ náà ṣeni ní kàyééfì bí àwọn ilé ìjọsìn kan ti ṣe ń kérora lórí òfin tó tako títa ọtí yìí nítorí pé àwọn kò ní ríbi jọ́sìn bó ti ṣe yẹ.

Ilé ìjọsìn kan tí wọ́n ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ghabola Church tó wà ní gúúsù olú ìlú Johannesburg ni àwọn ọmọ ìjọ bẹ̀ ti ní kí Ìjọba wá nǹkan ṣe sí òfin má ta ọtí yìí.

Nílé ìjọsìn àràmọ̀ndà tí à ń wí yìí, ìgbàgbọ́ wọn ni pé mímu ọtí lámupara jẹ́ ọ̀nà kan gbógì táwọn fi le bá Ọlọ́run ṣọ̀rọ̀ .

Gabola tí wọ́n fi sọrí ilé ìjọsìn náà túmọ̀ sí ọtí mímu ní èdè SeTswana.

Olùdásílẹ̀ ilé ìjọsìn náà Pope Tsietsi Makiti sàlàyé pé ”awọn kò kò kí Ìjọba ti àwọn mọ́lé títí di ìgbà tí Jesu yóó fi padà wá.”

Tsietsi tó jẹ́ ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́ta ṣàlàyé pé nǹkan bí ọdún méjì sẹ́yìn làwọn bẹ̀rẹ̀ Ilé ìjọsìn àwọn.

”Ní ilé ìjọsìn Gabola, o máa gbé ọtí rẹ wá, tí pásítọ̀ yóó sì bá ọ yà á sí mímọ́, kí ó má baà ṣe àkóbá f’ára à rẹ”

Ó ní nígbà tí òfin yii sì ti bẹ̀rẹ̀, ńṣe làwọn kò dúró lójú kan ṣe ìjọsìn, kí àwọn agbófinró má baà mú àwọn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…