Home ÀKỌ̀TUN Ọ̀pọ̀ èèyàn ń bèèrè pé kín ló dé tí Olorì Badra kò fi sí nínú fọ́tò ọdún Iléyá
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - August 5, 2020

Ọ̀pọ̀ èèyàn ń bèèrè pé kín ló dé tí Olorì Badra kò fi sí nínú fọ́tò ọdún Iléyá

Ọ̀pọ̀ èèyàn ń bèèrè pé kín ló dé tí Olorì Badra kò fi sí nínú fọ́tò ọdún Iléyá

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọjọ́ Ẹtì ni ọdún Iléyá wáyé f’ọ́dún yìí jákèjádò àgbáyé tí gbogbo ìdílé sì jókòó sílé láti se ayẹyẹ ọdún náà papọ̀.

Bákan náà sì ni ayẹyẹ yìí wáyé ní ààfin Ọ̀yọ́, níbi tí ikú Bàbá Yèyé, Ọba Lamidi Oláyíwọlá Adéyemí àtàwọn Olorì rẹ̀ ti se yàtà-yòtò ọdún.

Àsìkò tí wọ́n ń se ọdún yìí ni Ọba Adéyemí ké sí àwọn Olorì rẹ̀ láti wá fara kínra pẹ̀lú òun ní gbọ̀ngàn ìgbẹ́jọ́.

Àwọn ayaba kékeré náà, tí wọ́n jẹ́ ẹ̀lẹ̀ Daddy àti afẹ́fẹ́ tí Ọba Aláyélúwà náà fi ń mí, ni wọ́n rọ̀gbà yí baba ká, tó sì ya àwòrán pẹ̀lú wọn nínú ọlá ńlá rẹ̀.

Nínú àwòrán náà, tí àwọn ayaba ọ̀hún fi sójú òpó ayélujára wọn, ni àpapọ̀ àwọn ẹlẹ Daddy náà ti jẹ́ méje, dípò mẹ́jọ táa mọ̀ wọ́n mọ́ tẹ́lẹ̀ .

Ẹni tó bá sì se àkíyèsí àwòrán náà fínnífínní láti mọ èwo nínú àwọn Olorì ni kò sí nínú àwòrán náà, á ríi pé Olorì Badrat Olaitan Ajoke Adeyemi ni kò báwọn péjú ya fọ́tò lọ́jọ́ Iléyá.

Ọ̀nà láti bá baba láàfin se àyẹ́si àwọn Olorì náà ló mú kí àwòrán náà ó wá sójú òpó abẹ́yefò Facebook .

Ṣùgbọ́n ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé ìbéèrè tó gba ẹnu ọ̀pọ̀ olólùfẹ́ Ọba Adeyemi lásìkò tí wọ́n fojú kan àwòrán náà ni pé:

Kí ló mú Olorì Badra kúrò l’Alaafin Ọ̀yọ́ lọ́jọ́ Iléyá, tí kò fi bá àwọn ayaba yókù ya àwòrán pẹ̀lú ọkọ wọn lọ́jọ́ ọdún?

Kódà ọ̀pọ̀ nínú àwọn èèyàn yìí ló tún ń bèèrè pé, àbí tòótọ ni ìròyìn tó jà ràn-ìn ràn-ìn láìpẹ́ yìí pé, Aláàfin ti lé Olorì Badrat jáde kúrò nínú ààfin rẹ̀ lórí ẹ̀sùn aṣemáṣe?

Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé, ìròyìn náà ló fẹ̀sùn kan Olorì Badrat Olaitan Ajọke Adeyemi pé ó ń ní ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀ pẹ̀lú ọba olórin fuji kan, Alhaji Wasiu Ayinde Kwam 1.

Ìròyìn náà fikún un pé, ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ló mú kí Ọba Adeyemi já okùn ìfẹ́ tó wà láàrin rẹ̀ àti Olorì Badrat, tó sì ní kó jáde kúrò nínú ààfin.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olorì Badrat àti Wasiu Ayinde sẹ́ pé àhesọ ọ̀rọ̀ lásán ni ìròyìn náà, òfúùtù-fẹ́ẹ̀tẹ̀, ni.

Àmọ́ kò sí àtẹ̀jáde kankan tó wá láti ààfin Ọ̀yọ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tí kò sì sí ẹni tó leè fìdí rẹ̀ múlẹ̀, bóyá Olorì Badrat sì wà nínú ààfin àbí ó ti kó kúrò.

Ṣùgbọ́n ohun tí a ṣàkíyèsí ni pé, Olorì náà kò fi bẹ́ẹ̀ gbé àwòrán òun àti ọkọ rẹ̀, Aláàfin sójú òpó ayélujára rẹ̀, gẹ́gẹ́ bó se máa ń se.

Bákan náà, kò sí àjọṣepọ̀ mọ́ láàrin rẹ̀ àti àwọn Olorì Aláàfin tó kù lójú òpó ayélujára, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti máa ń se tẹ́lẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ sì ni Olorì Memunat Omowunmi Adeyemi tí òun àti Olorì Badrat Olaitan dìjọ jẹ́ kòrìkósùn nínú ààfin gan, ni wọ̀n kò dìjọ se bíi ti àtijọ́ mọ́.

Àṣà àwọn Olorì Aláàfin ni pé kí wọ́n máa kí ara wọn kú ayẹyẹ ọjọ́ ìbí tara wọn tàbí ti ọmọ wọn.

Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ti wáyé, kò sí Olorì Aláàfin kankan tó kí Ayaba Badrat kú ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀, tí òun náà kò sì kí ẹnikẹ́ni nínú wọn.

Bóyá lásìkò tí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí wọn bá kò tàbí tàwọn ọmọ wọn, èyí tó ń kọ ọ̀pọ̀ òǹwòye lóminú.

Ìdí sì rèé tí ọ̀pọ̀ èèyàn tún fi ń bèèrè pé ‘Níbo ni Olorì Badrat Ajoke wà lásìkò pọ̀pọ̀sìnsìn ọdún Iléyá?

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …